Baba mi lo nifẹẹ si iṣẹ ṣọja, nitori tiwọn ni mo ṣe wa nileewe naa bayii – Lọọya Kunle

Ọdọmọde ni, nitori ọjọ ori rẹ ko ju mẹẹẹdọgbọn(25), lọ. Ṣugbọn iṣẹ adẹrin-in-poṣonu to n ṣe a maa mu awọn agbalagba ti wọn ju u lọ daadaa rẹrin-in arintakiti, bẹẹ naa lo si jẹ aayo awọn ọdọ iwoyi naa lori awọn ikanni bii Fesibuuku, Instagraamu ati Tuita(Twitter).

Eeyan to n tẹle e lẹyin gẹgẹ bii ololufẹ lori Instagraamu le ni miliọnu kan(1.1 million followers), bo si ṣe n ṣẹfẹ naa lo tun jẹ ṣọja to n kọṣẹ ologun lọwọ.

Lọọya Kunle la n sọ nipa ẹ, oun naa ni wọn n pe ni ‘Ankara Gucci, awọn mi-in a si maa pe e ni ‘The Cute Abiola. Eyi ni ifọrọwerọ to waye laarin oun ati ADEFUNKẸ ADEBIYI lọsẹ to kọja, ẹ jẹ gbadun ẹ.

AKEDE AGBAYE: Lọọya Kunle, Ankara Gucci ati The Cute Abiola lawọn eeyan n mọ yin si, ki lorukọ yin gan, ọmọ ilu wo si ni yin?

LỌỌYA KUNLE: Orukọ mi ni Abdulgafar Ahmed Abiọla. Ọmọ Ilọrin ni mi, nipinlẹ Kwara.

AKEDE AGBAYE: Awọn ileewe wo lẹ lọ?

LỌỌYA KUNLE: Mo lọ si Iqra Nursery and Primary School. Mo lọ si Iqra College, mo tun lọ si Model Secondary School naa. Mo lọ si Kwara Poli. Ilọrin ni gbogbo ileewe yii wa.

AKEDE AGBAYE:Ẹ wa lẹnu ẹkọṣẹ iṣẹ ṣọja lọwọ, ẹ tun n ṣe ẹfẹ lori ẹka ayelujara. Awọn ṣọja ko raye ẹfẹ, bawo lẹ ṣe n mu un pọ ti ko pa ara wọn lara?

LỌỌYA KUNLE: Ọlọun naa lo n jẹ ko maa yiisi. Ninu gbogbo ohun teeyan ba n ṣe laye yii, ko maa fi eto si i.Mo n ṣe gbogbo ẹ mọra wọn naa ni, loootọ, o n pa ara wọn lara o,ṣugbọn ko han saye bi mo ṣe n ṣe e.

 AKEDE AGBAYE:Nigba tẹ ẹ ṣọjọọbi lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun yii, ẹ faṣọ ṣọja yin ya fọto, awọn ṣọja si binu, wọn gbe e yin lọ fun ibawi. Alaye wo lẹ le ṣe lori eyi?

LỌỌYA KUNLE:Ma a fẹ kẹ ẹ jẹ ka fi idahun yẹn silẹ, mi o ti i le sọrọ nipa ẹ lasiko yii ti mo ṣi wa lẹnu ẹkọṣẹ naa lọwọ. To ba di lọjọ iwaju ti mo ba pari, ti mo di ologun, ma a sọ ọ.

Looya Kunle ninu aso soja ori-omi

AKEDE AGBAYE: Ẹ tiẹ sọ pe ẹkọṣẹ ologun yẹn ko rọrun nigba kan, ẹ ni ẹ fẹẹ kuro nibẹ, bawo ni bayii?

LỌỌYA KUNLE:  Ẹkọṣẹ ologun(Training) ki i ṣe nnkan to rọrun rara, loootọ ni mo kọ ọ sita nigba yẹn pe mo fẹẹ kuro, nitori ko rọrun ni. Ṣugbọn iṣẹ yẹn naa jẹ iṣẹ ti baba mi nifẹẹ si, eeyan ko dẹ mọ nnkan teeyan fi n ṣẹ obi ẹ, nitori tiwọn ni mo ṣe n ṣe e lọ. Ati pe mo gba pe teeyan ba ti kara bọ nnkan kan, afi ko gba bo ba ṣe ri. Mo ṣi wa lẹnu ẹ, mi o kuro mọ.

AKEDE AGBAYE: Ẹnikan fun yin ni mọto lọjọ ayẹyẹ ọjọọbi naa, ta ni tọhun?

LỌỌYA KUNLE: Ootọ ni.Ẹni yẹn jẹ ẹnikan to maa n gba mi niyanju lati ma jẹ ko su mi nigba ti mo ṣẹṣẹ bẹrẹ kọmẹdi. Alatilẹyin mi ni latilẹ,ẹni yẹn n ta mọto niluu oyinbo ati ni Naijiria naa. Mi o tiẹ fọkan si i, asiko igbele ni,ile ni mo wa ti wọn fi gbe e wa, inu mi dun gan-an lọjọ naa.

AKEDE AGBAYE:Bawo lẹ sẹ bẹrẹ Kọmẹdi ọhun gan-an?

LỌỌYA KUNLE: Kọmẹdi gan-an kọ ni mo fẹẹ ṣe tẹlẹ, iṣẹ lọọya lo wu dadi mi pe ki n ṣe. Igba ti mi o waa lanfaani lati wọ yunifasiti,mo lọ si poli. Ṣugbọn kọmẹdi yẹn ti wa lara mi tipẹ, lati ileewe girama ni mo ti nifẹẹ si ka maa ṣere tabi ẹfẹ. Bi mo ṣe kuku tẹra mọ ọn niyẹn.

Ipari 2010 ni mo bẹrẹ si i ṣe adari eto lode inawo titi wọ 2011 ti mo tun mu skit ṣiṣe mọ ọn. Ko yiisi nigba yẹn, mo kan n fori ti i ni. 2017 ni Ọlọun gbadua.

AKEDE AGBAYE:Awọn nnkan daadaa wo ni skit ṣiṣe yii ti mu ba yin bayii?

Skit ṣiṣe ti mu mi mọ ọpọlọpọ eeyan, mo mọ awọn olori ilu, mo mawọn eeyan pataki lawujọ. Ko sibi ti mo fẹẹ wọ ti wọn yoo fọwọ rọ mi da sẹyin, ọpọlọpọ ilẹkun anfaani lo ti ṣi fun mi.

Mo fi n ran awọn obi mi lọwọ, mo fi n ṣaanu fawọn eeyan, emi naa dẹ n na an funra mi, nitori igbesi aye gbajumọ(celebrity) ko rọrun.

AKEDE AGBAYE: Ẹyin ọmọde ẹlẹfẹ asiko yii ni aṣa kan, aṣọ kan ṣoṣo lẹ n wọ ṣiṣe lọpọ igba.

A mọ LizzyJay(Ọmọọbadan) mọ lesi iro ati buba, agbada ati fila ni ti Mista Macaroni, ṣẹẹti kan bayii ni ti Lọọya Kunle, ṣe nitori idanimọ naa ni?

LỌỌYA KUNLE: Nitori idanimọ, ati nitori pe awọn ẹfẹ wa yẹn maa n tẹsiwaju nigba mi-in. Pataki ibẹ waa ni pe bawọn eeyan ba ti ri aṣọ yẹn lọrun wa, awọn ẹlomi-in aa ti maa rẹrin-in silẹ ki wọn tiẹ too gbọ ohun ti skit naa da le lori. Nitori ẹ la ṣe n wọṣọ kan ṣoṣo, ki i ṣe pe ko daa keeyan paarọ aṣọ.

AKEDE AGBAYE: Njẹ ẹ ranti ‘skit’ tẹ ẹ kọkọ ṣe mọ?

LỌỌYA KUNLE: Bẹẹ ni, mo ranti.O yatọ si eyi to jẹ kawọn eeyan mọ mi. Oun ni eyi ti mo ti n bu awọn nẹtwọọki pe wọn ja kaadi mi, pe ki wọn da a pada abi ki n fun wọn lepe. Eyi tawọn eeyan fi waa mọ mi ni ‘Ankara Gucci’, nibi ti mo ti ni a fẹẹ ṣenawo, Ankara Gucci la dẹ maa mu.

Looya Kunle lasiko ere awada

AKEDE AGBAYE: Awọn obinrin ọlọmu nla, oni bakasi rabata maa n wa ninu awọn skit yin,ṣe bẹẹ naa lẹ nifẹẹ wọn loju aye?

LỌỌYA KUNLE: Mo kan n fiyẹn ṣere ni, emi o kundun awọn nnkan bẹẹ. Ẹni ti mo n fẹ gan-an ko ri bẹẹ yẹn.Ko dẹ ki i ṣe gbogbo igba naa la maa n ṣe awọn nnkan bẹẹ.Mo n lo awọn obinrin to sanra ki wọn le mọ pe ko si bawọn ṣe ri tawọn ko ni i ri ọkunrin to laiki awọn, ki wọn ma baa maa ro ara wọn pin ni.

AKEDE AGBAYE: Ṣe ẹ ti ṣegbeyawo, awọn ọmọ nkọ?

LỌỌYA KUNLE:Mi o ti i gbeyawo, ṣugbọn mo ti ni afẹsọna, mi o ti i bimọ.

AKEDE AGBAYE:Ounjẹ wo lẹ fẹran ju?

LỌỌYA KUNLE:  Okele ni, ko ṣaa ti jẹ okele. Mo maa n jẹun daadaa.

 AKEDE AGBAYE: Ọna wo lẹ n gba ṣe faaji bi ẹ ko ba si lẹnu iṣẹ?

LỌỌYA KUNLE: Mo maa n nifẹẹ lati ṣe faaji pẹlu awọn alaini, ki n fun wọn ni nnkan. Ki i ṣe gbogbo nnkan leeyan n gbe si Fesibuuku. Emi o ki i muti, mi o dẹ ki n lọ si kilọọbu. O tẹ mi lọrun ki n ba awọn ti ko to mi ṣe, inu mi dẹ maa n dun ti wọn ba ṣadua fun mi.

Leave a Reply