Baba ọgọrin ọdun to fipa ba ọmọ ọdun marun-un lo pọ l’Agege loun fẹẹ fẹ ẹ ni

 Faith Adebọla

Tika-tẹgbin lawọn eeyan n wo baba ẹni ọgọrin ọdun kan, Ebenezer Ọlaiya Oyewọle, nigba tawọn agbofinro wọ ọ tuuru l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ  yii de iwaju adajọ ni kootu Majisreeti to wa lagbegbe Ọgba, nipinlẹ Eko, lori ẹsun pe o fipa laṣepọ pẹlu ẹgbẹ ọmọ-ọmọ ẹ, ọmọ ọdun marun-un pere. Adajọ ti ni ko ṣi wa lẹwọn na.

Opopona Aranṣe Olu, l’Agege, ni wọn ni baba naa n gbe, ibẹ naa lo ti huwa idọti ọhun, ile kan naa yii lọmọbinrin ọhun si n gbe pẹlu awọn obi ẹ.

Ninu alaye ti Agbefọba, Supol Bisi Ogunlẹyẹ, ṣe nigba ti wọn n ka ẹsun si baba naa leti, o ni iwadii tawọn ṣe fi han pe niṣe ni olujẹjọ yii dọgbọn tan ọmọbinrin naa wọ yara rẹ, wọn lọmọbinrin naa sọ pe baba yii lo bọ pata nidii oun lọjọ ọhun, to si ki oun mọlẹ, to fipa ba oun sun.  Lẹyin to tẹra ẹ lọrun tan ni wọn lo halẹ mọ ọmọ ọhun pe ko gbọdọ sọ fẹnikan o, tori oun fẹẹ fẹ ẹ ni to ba ya.

Wọn lawọn ọrẹ ọmọbinrin ọhun kan to kọkọ sọ fun ni wọn ṣofofo iṣẹlẹ naa fun mama rẹ, ki ọmọbinrin naa too ṣalaye ohun ṣẹlẹ, lawọn obi naa ba lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni teṣan wọn.

Nigba tawọn ọlọpaa mu baba naa, akata ẹka to n ri si iwa ọdaran abẹle ni kọmandi ọlọpaa Ikẹja ni wọn taari ẹ si, ti wọn bi i leere ọrọ, wọn ni Ebenezer ko jampata, o ni loootọ loun bọ pata nidii ọmọbinrin naa, loootọ loun si ba a laṣepọ, o ni oun laiki ọmọ naa ni.

Ogunlẹyẹ ni iwa ti baba arugbo yii hu ta ko iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, ẹwọn gbere si nijiya ẹṣẹ yii ti wọn ba lo jẹbi.

Nigba ti wọn ni ko sọrọ niwaju adajọ, niṣe ni baba naa n gbọn, gbogbo ohun to le sọ ni pe kile-ejọ ṣaanu oun, ki wọn jẹ koun maa ti ile waa jẹjọ, ki wọn foun ni beeli.  Abilekọ E. Kubenje lo wa lori aga idajọ, ko si wo afurasi ọdaran naa lẹẹmeji to fi da ẹbẹ rẹ nu bii omi iṣanwọ. Adajọ ni ko saaye beeli fun un rara, ọgba ẹwọn Kirikiri nile ni ko ti lọọ maa gbatẹgun titi di ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an, to n bọ yii. O ni ki wọn tete fi faili rẹ ṣọwọ si ajọ to n gba awọn adajọ nimọran, ki wọn le mọ igbesẹ to kan.

Kubenje ni bi oun ṣe n wo ọrọ ọhun, afaimọ ki oun maa fi keesi naa ṣọwọ sile-ẹjọ giga laipẹ.

Leave a Reply