Ọlọfaana tọrọ aforiji lọwọ awọn oṣere-binrin Yoruba fun ọrọ to sọ si wọn

Baba Ọlọfaana ti tọrọ aforiji lọwọ awọn oṣere tiata obinrin fun ọrọ to sọ, paapaa fun bo ṣe ni pupọ ninu awọn onitiata obinrin ni wọn maa n ba ni ibalopọ lagbo oṣere. Ṣe ẹ ranti pe Baba naa ni ko jẹ tuntun pe ibalopọ n waye laarin awọn oṣere tiata nigba to n ba ALAROYE sọrọ ni kootu ti wọn ti gbọ ẹjọ Baba Ijẹṣa lọsẹ to kọja.

Ninu fidio kan to fi lede, Olofaana tọrọ aforiji, o sọ pe kawọn eeyan ma ṣi oun gbọ o, oun ko ṣegbe lẹyin ki wọn maa fi ipa  ba obinrin tabi ọmọde lo pọ.

O ni ara lo ta oun to mu ki oun sọ ohun toun sọ lọgba kootu Ikẹja yẹn, ohun toun si ni lọkan kọ lawọn eeyan n tumọ ọrọ naa si.

O fi kun pe, “Ẹma binu ana, paapaa ẹyin obinrin ti ẹ jẹ iya wa nidii iṣẹ tiata.”

Agba ọjẹ naa ṣọ siwaju si pe ki i ṣe aṣa awọn onitiata ni lati maa fi ọwọ pa obinrin lara lọna aitọ nitori ẹṣẹ ni niwaju Ọlọrun, bẹẹ lo si ṣalaye pe awọn obinrin onitiata ki i ṣe aṣẹwo o, o ni kawọn ọkunrin ti ibalopọ lọna aitọ ba ti wọ lẹwu tete yaa mọ bi wọn ṣe maa jawọ nibẹ.

Leave a Reply