Baba ọmọ to ku lọsibitu FMC, l’Abẹokuta, la aga mọ dokita lori, o ni ko tete tọju ọmọ oun lo fi ku

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 

Ko si ọrọ meji tawọn eeyan n sọ nipa ọsibitu Federal Medical Center (FMC), to wa n’Idi-Aba, l’Abẹokuta, bayii ju ti ọkunrin kan ti ọmọ rẹ ku si ọsibitu naa lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja, to si mu ọkan ninu awọn dokita to tọju ọmọ naa lu bii ko ku, to tun la aga mọ ọn lori lọpọ igba kawọn eeyan too gba dokita naa silẹ lọwọ rẹ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila oru ọjọ Ẹti naa ti i ṣẹ ọjọ kejila, oṣu kẹta yii, niṣẹlẹ naa waye, iyẹn lẹyin iku ọmọ ọdun kan ati oṣu mẹta naa. Wọọdu awọn ọmọde ni wọn gba ọmọbinrin naa si fun aarẹ to n ṣe e, ṣugbọn aisan lo ṣee wo lọrọ naa pada ja si, niṣe lọmọ ọhun ku nibi ti wọn ti n tọju rẹ.

Ṣugbọn ẹsẹkẹsẹ ti awọn dokita tufọ iku ọmọde yii fun baba rẹ ni wọn ni ọkunrin naa binu rangbọndan, niṣẹ lo si doju kọ dokita to tufọ naa, lo bẹrẹ si i lu u. Koda, ṣia to wa nitosi ni wọn ni ọkunrin naa ki mọlẹ, to la mọ dokita naa lori, bi ko si ṣe pe awọn eeyan tete gba a silẹ lọwọ baba naa, Ọlọrun lo mọ ohun ti ko ba ṣẹlẹ si dokita ọhun.

Ohun to bi baba ọmọ yii ninu gẹgẹ ba a ṣe gbọ ni pe o ni awọn dokita ileewosan FMC ko tete bẹrẹ itọju fun ọmọ oun ni, to fi di pe nnkan bajẹ to bẹẹ ti ọmọ si pada ku.

Ṣugbọn ninu atẹjade ti Ọgbẹni Ṣẹgun Orisajo, ti i ṣe Alukoro ọsibitu naa fi sita, o ni ọsibitu yii ko ni i fara mọ ifiyajẹni ti awọn to n gbe alaisan wa n foju awọn oṣiṣẹ awọn ri mọ.

Lori eyi to ṣẹlẹ yii, Orisajo sọ pe ọga agba ileewosan naa, Ọjọgbọn Musa Olomu, ti kilọ pe o to gẹẹ, nitori eyi to ṣẹlẹ yii ni ẹlẹkẹẹrin ẹ ti awọn to waa gba itọju yoo lu dokita nileewosan FMC, bẹẹ laarin asiko diẹ sira wọn ni.

Nigba to n ṣalaye siwaju si i lori iku ọmọde yii, Orisajo sọ pe lati oṣu kan sẹyin ni akọ iba ti n ṣe ọmọ kekere naa, o ti ru gidi, ṣugbọn awọn obi rẹ ko gbe e wa sọsibitu nigba yẹn.

O ni ọmọde naa n kanra, bẹẹ ni ọrun rẹ paapaa ko duro daadaa mọ latari aarẹ to n ṣe e lara. O ni bi wọn ṣe gbe ọmọ naa de lawọn gbe e wọ yara itọju pajawiri (Emergency ward) lọdọ awọn ọmọde, bo si tilẹ jẹ pe ọpọ nnkan to yẹ ki baba rẹ ra fun itọju rẹ lo n sọ pe oun ko rowo ra, sibẹ, Orisajo sọ pe ọsibitu naa foju fo o da, wọn bẹrẹ si i tọju ọmọdebinrin naa gẹgẹ bi ilana ẹkọ iṣegun ti wọn gba, wọn fẹẹ gba ẹmi rẹ la dandan.

Ṣugbọn lẹyin wakati mẹrin ti wọn ti n ṣe eyi, ọmọ naa ku, ko si sohun ti ẹnikẹni le ṣe si i. Boya ka ni wọn tete gbe ọmọbinrin naa wa lasiko ti aarẹ naa ti n ṣe e lati oṣu kan sẹyin, o ṣee ṣe ko ma ku ni awọn ara ọsibitu naa wi, ṣugbọn nigba ti wọn de e mọlẹ fọjọ pipẹ, aarẹ naa ti wọ ọ lara kọja ibi to yẹ lo ṣe ja si iku fun un.

Lati tun mọ bo ṣe ṣẹlẹ gan-an, ALAROYE pe Ọgbẹni Orisajo lori foonu laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ọkunrin naa sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, nitori ẹ lawọn ko ṣe darukọ ọkunrin to lu dokita naa ati orukọ dokita to lu.

O ni ṣugbọn ọkunrin ni dokita ọhun, lilu naa pọ debii pe gbogbo oju dokita naa lo wu, to si n ṣẹjẹ.

Ṣugbọn gbogbo eyi lo ni FMC koro oju si, ohun to ni o yẹ kawọn obi maa ṣe ni lati tete gbe ọmọ to ba rẹ wa si ọsibitu, ki i ṣe pe ki wọn duro nile titi ti nnkan yoo fi bajẹ pata, ti wọn yoo waa maa lu dokita ti ki i ṣe oun lo pa wọn lọmọ.

 

Leave a Reply