Baba to fipa ba awọn ọmọ bibi inu ẹ mẹta lo pọ ti dero Kirikiri

Faith Adebọla, Eko

Ile-ẹjọ Majisreeti to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, ti paṣẹ pe ki wọn ṣi lọọ tọju baale ile ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Emeka Orisakwe, sọgba ẹwọn Kirikiri, l’Ekoo na, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o fipa ba mẹta lara awọn ọmọ ẹ lo pọ.

Awọn ọlọpaa ni wọn wọ afurasi ọdaran naa lọ sile-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee yii.

Agbefọba, ASP Bisi Ogunlẹyẹ, ṣalaye nigba to n ka ẹsun ti wọn fi kan Emeka ni kootu pe laarin oṣu karun-un si oṣu keje, ọdun yii, lọkunrin naa huwa palapala ọhun nile rẹ toun atawọn ọmọ naa n gbe laduugbo Maza-Maza, lagbegbe Amuwo Ọdọfin, l’Ekoo.

O lọjọ-ori eyi to dagba ju lọ ninu awọn ọmọbinrin ọhun jẹ ọmọ ọdun mẹjọ, ekeji jẹ ọmọọdun mẹfa, ọmọọdun mẹrin pere ni ẹkẹta wọn, ọmọ bibi ẹ si lawọn mẹtẹẹta.

Ogunlẹyẹ ni awọn ti ko awọn ọmọ naa lọ fun ayẹwo, awọn oniṣegun si ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ lẹnikan ti ṣe awọn ọmọ ọhun baṣubaṣu, tawọn ọmọ naa si jẹwọ pe baba awọn lo wa nidii iwa ibajẹ naa, leyii to ta ko isọri ọtalerugba ati ẹyọ kan (261) ninu iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, tọdun 2015.

Nigba tọrọ kan Emeka, o loun ko jẹbi pẹlu alaye, ṣugbọn Adajọ Ejiro Kubeinje sọ p’oun o tiẹ fẹẹ gbọ alaye kankan lẹnu ẹ lasiko yii, o ni ki wọn taari ẹ sọgba ẹwọn ni, ibẹ ni ko ti maa gbatẹgun titi di ọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun yii, ti yoo tun foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply