Baba to fipa ba ọmọ ọdun mejila lo pọ l’Ejigbo ni pasitọ ṣọọṣi awọn lo sa soun

Faith Adebọla, Eko

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ, ni ireti wa pe baba ẹni ọdun mẹtadinlaaadọrin kan, James Ọlajoyetan, yoo bẹrẹ si i wi tẹnu rẹ niwaju adajọ lori ẹsun fifipa ba ọmọ ọdun mejila lo pọ ti wọn fi kan an.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Muyiwa Adejọbi, sọ f’ALAROYE lori foonu l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, pe iṣẹ iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan baba naa ti fẹẹ pari, igbesẹ to kan ni ki baba naa lọọ ṣalaye ara ẹ niwaju adajọ, ẹsẹkẹsẹ si lawọn si fẹ kigbesẹ naa waye.

Ohun ta a gbọ ni pe agbegbe Ejigbo, nijọba ibilẹ Oṣodi/Isọlọ, nipinlẹ Eko, ni baba ti wọn lo n ṣiṣẹ ọkada gigun yii n gbe, agbegbe naa si lọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri ọhun wa.

Inu ọdun Ileya to kọja, ninu oṣu keje yii, ni wọn lọmọbinrin ọhun waa ba baba rẹ agba ṣọdun, o si duro lati ran baba naa lọwọ, tori baba agba naa ni iṣoro oju, ko riran daadaa.

Wọn ni niṣe ni afurasi ọdaran naa dibọn lọjọ kan pe oun fẹẹ ran ọmọbinrin ọhun niṣẹ, lo ba tan an wọle, o fun un ni ọgọrun-un naira, ṣugbọn kaka ko jẹ ki ọmọ naa jade, niṣe lo tilẹkun yara ẹ, lo ba bẹrẹ si i fipa ba a lo pọ.

Koda, wọn lọmọbinrin naa ni igba mẹrin ọtọọtọ ni baba naa ti ba oun sun, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa jẹwọ pe ẹẹkan pere niṣẹlẹ naa waye.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ti awo ọrọ ya, ẹnikan ni wọn lo gba ibi ferese yara baba naa kọja, to si n gbọ bi ọmọbinrin naa ṣe sunkun labẹnu, lo sọ ohun to ṣẹlẹ fawọn to wa laduugbo naa. Eyi lo mu ki wọn yọju loju windo, iyalẹnu lo jẹ bi wọn ṣe ri baba agbaaya yii nihooho lori ọmọ yii.

Awọn aladuugbo ọhun ni wọn wọ baba naa de teṣan ọlọpaa Ejigbo, tawọn ọlọpaa fi sọ ọ sahaamọ, ti wọn si taari rẹ sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n wadii iwa iṣekuṣe abẹle ni ileeṣẹ wọn to wa ni Panti, ni Yaba.

Ni teṣan ọlọpaa, wọn lọkunrin tiyawo rẹ ti ku tipẹ naa jẹwọ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe pasitọ ṣọọṣi CAC toun n lọ ni Kajọla lo ṣepe foun, o loun ati Pasitọ naa ni aawọ nigba toun fẹẹ fi ṣọọṣi naa silẹ loṣu mẹrin sẹyin, o ni pasitọ naa si fibinu ṣepe pe oun maa ṣẹsin, oun maa ṣẹlẹya. O ni epe naa lo n ja oun, tori oun o tiẹ mọ ohun to gbe oun dedii palapala bii eyi.

O lọmọ mẹfa loun bi, akọbi oun si ti le lẹni ọdun marundinlogoji, abikẹyin oun ti dọmọ ọdun mẹtadinlogun, ko ye oun bo ṣe le jẹ pe ọmọ ti ko to ẹgbẹ abikẹyin oun loun wa n ba lopọ yii.

Ṣugbọn boya epe lo n ja James, abi o mọ-ọn-mọ huwa ọhun ni, nigba to ba dewaju adajọ ni yoo maa ṣalaye.

Leave a Reply