Baba to na ọga ileewe girama nitori ọmọ rẹ ti foju bale-ẹjọ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Baba kan, Adeyẹni Adeyẹye, ti foju bale-ẹjọ Majisreeti ilu Ileefẹ lori ẹsun pe o na ọga agba ileewe Oduduwa College, Ọgbẹni Sanusi Ademọla.

Aago mẹwaa aabọ aarọ ọjọ kin-in-ni, oṣu keji, ọdun yii, la gbọ pe Sanusi lẹdi apo pọ mọ awọn kan ti wọn ti sa lọ bayii lati jẹ Sanusi niya.

ASP Abdullahi Emmanuel to jẹ agbefọba ṣalaye pe ṣe ni Sanusi ko awọn tọọgi lọ sinu ọgba ileewe naa, ti wọn faṣọ ya mọ Sanusi to jẹ ọga ileewe naa lara lẹyin ti wọn na an tan.

Bakan naa ni wọn tun na obinrin kan, Awoyẹye Ọlayide, ti wọn si tun ji kọkọrọ mọto pẹlu pọọsi rẹ ti owo to to ẹgbẹrun lọna aadọta naira (#50,000) wa ninu ẹ.

Ẹsun mẹfa ni wọn fi kan olujẹjọ yii, lara wọn ni igbimọ-pọ lati huwa buburu, ole jija, kikọlu eeyan, biba nnkan jẹ, hihuwa to le da omi alaafia agbegbe ru ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lẹyin ti wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun naa ni agbẹjọro wọn, Oluwatosin Ademọla, bẹbẹ fun beeli wọn pẹlu ileri pe wọn ko ni i sa lọ fun igbẹjọ.

Majisreeti A. A. Adebayọ fun un ni beeli pẹlu miliọnu kan naira ati oniduuro kan. O ni oniduuro naa gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba to wa nipele kejila.

Adebayọ fi kun un pe oniduuro naa gbọdọ mu lẹta ti wọn fi gba a siṣẹ ati eyi to fi gba igbega gbẹyin wa si kootu, bẹẹ lo si gbọdọ maa gbe lagbegbe kootu.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹta, oṣu kẹta, ọdun yii.

A oo ranti pe ṣe ni Ọgbẹni Sanusi ba Adeyẹni Adejuwọn to wa ni kilaasi SSS3 nileewe naa wi pẹlu bo ṣe mura, ni ọmọ naa ba lọ sile, o lọọ fẹjọ sun baba rẹ, ni baba ba ko awọ tọọgi lọ sileewe naa, wọn si lu ọga ileewe yii lalubami lọjọ ọhun.

Leave a Reply