Mo fọwọ si Ọṣinbajo lati dupo aarẹ, eeyan daadaa ni, o si ni ero rere-Babangida

Faith Adebọla

Olori orileede wa laye ologun, Ajagun-fẹyinti Ibrahim Badamọsi Babangida ti fi atilẹyin rẹ han si Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lati jade dupo aarẹ ilẹ wa ninu eto idibo to n bọ lọdun 2023, o leeyan daadaa ni, o si lero rere nipa Naijiria.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, ni Babangida fi idunnu rẹ han nigba tawọn ololufẹ Igbakeji Aarẹ ti wọn wa ninu ẹgbẹ Oṣinbajo Grassroot Organisation, (OGO) lọọ ṣabẹwo ‘ẹ n lẹ n bẹun’ si Babangida nile rẹ to wa niluu Minna, nipinlẹ Niger.

Ẹgbẹ OGO yii ni wọn fi n ṣe kokaari awọn ololufẹ Ọṣinbajo, ti wọn si fi n wa awọn alatilẹyin fun erongba rẹ lati dupo aarẹ lọdun 2023, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ko ti i kede ni gbangba pe oun fẹẹ dupo naa.

Nigba to n sọrọ lasiko abẹwo naa, Babangida ni: “Mo ti mọ Igbakeji Aarẹ tipẹtipẹ, mo si mọ ọn daadaa. Eeyan rere ni, ọkunrin daadaa si ni pẹlu. Ẹni to ni afojusun pato nipa Naijiria ni, ẹni to le bawọn eeyan sọrọ, to si le ta wọn ji ni. Iru ẹni to yẹ keeyan ba ṣiṣẹ pọ ni.

“A nilo eeyan rere to maa ṣaaju orileede Naijiria, eeyan ti ọrọ orileede yii ka lara gidi, ti ifẹ ilu rẹ si jẹ lọkan. Orileede atata ni Naijiria, awọn eeyan atata lo si wa ninu rẹ, eeyan gbọdọ loye awọn to n gbe’bẹ daadaa ni, ko si loogun meji, ijumọsọrọpọ ati ifikunlukun atigbadegba loogun ẹ.

“Mo fẹẹ fi idaniyan rere mi si Igbakeji Aarẹ han ni o, mo si fẹ kẹ ẹ ba mi sọ fun un pe ko maa ba daadaa ẹ lọ. Mo mọ pe ko rọrun, ṣugbọn ko ma juwọ silẹ, tori awọn afojusun rere to wa lọkan ẹ. Mo gbagbọ pe didun lọsan maa so nigbẹyin.”

Babangida ni tori oun mọ iru ẹni ti Ọṣinbajo jẹ, oun si mọ pe iṣẹ kekere kọ ni keeyan too le jẹ aṣaaju rere, idi toun fi gba ẹgbẹ OGO laaye lati ṣabẹwo soun niyẹn, ti oun si ba wọn sọrọ.

Ninu ifesipada rẹ, Alakoojọ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Ojo Foluṣọ, ni inu awọn dun si ọrọ ti Babangida sọ nipa Ọṣinbajo yii.

Foluṣọ ni: A ti waa ba Ifa ni gbolohun, Ifa si ti fọre. Amọran bii Ifa ni Babangida, tori ko sẹni to loye Naijiria to o.”

Leave a Reply