Babatunde ati Akinpẹlu lu oyinbo ni jibiti, wọn ti mu wọn o

Oluyinka Soyemi

Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti jibiti ori intanẹẹti, labẹ agbarijọpọ ikọ ọlọpaa agbaye (INTERPOL),  ti mu awọn meji kan, Babatunde Adesanya ati Akinpẹlu Hassan Abass, lori ẹsun pe wọn lu ileeṣẹ kan to jẹ tilẹ Germany ni jibiti.

Aṣọ tawọn to n ṣetọju ẹni to ba ni arun Koronafairọọsi n lo, eyi ti wọn n pe ni Personal Protective Equipment (PPE), lawọn ọlọpaa sọ pe awọn afurasi ọhun  ni awọn yoo ta fun ẹnikan, ẹni naa si ro pe ileeṣẹ to n ta a lo n ba oun sọrọ lai mọ pe o ti ko sọwọ onijibiti.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede yii, Frank Mba, fi sita, Adesanya to jẹ ẹni aadọta ọdun ati Akinpẹlu, ẹni ọdun mọkanleogoji to jẹ alaṣẹ the M.D of Musterpoint Investment Nig. Ltd, ni wọn jọ n ṣiṣẹ pẹlu awọn onijibiti agbaye mi-in.

Mba ni aṣọ PPE towo ẹ sun mọ miliọnu mẹẹẹdogun yuro lawọn afurasi yii sọ pe awọn fẹẹ ta fun ọkunrin kan to n jẹ Freiherr Fredrick Von Hahn nilẹ Holland, ẹka intanẹẹti ileeṣẹ ILBN Holdings BV to wa niluu naa ni wọn si fi ba ọkunrin naa sọrọ, eyi to jẹ ko ro pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ni wọn ba oun dunaa-dura.

Lẹyin naa ni wọn gba miliọnu kan aabọ yuro lọwọ ẹ, wọn tun gba owo to sun mọ ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹẹdẹgbẹrin (880,000) yuro, nigba ti ọkunrin naa ko si ri ọja to fẹẹ ra gba lo lọ si ẹka ileeṣẹ ọhun to wa niluu Holland, nibi to ti han pe awọn mi-in lo ba sọrọ.

Alukoro ọlọpaa ọhun sọ siwaju pe nigba ti iwadii awọn ọlọpaa agbaye ti wọn n pe ni INTERPOL bẹrẹ iwadii ni wọn mu awọn meji kan, Eduardus Boomstra ati Geradius Maulder, nilẹ Holland, o si pada han pe ṣe ni wọn n ṣiṣẹ pẹlu Babatunde ati Akinpẹlu.

Itẹsiwaju iwadii naa lo ni ijọba ilẹ Germany rọ ilẹ Naijiria lati ṣe, eyi lo si pada yọri si bi ọwọ ṣe tẹ awọn afurasi meji wọnyi, akọsilẹ si wa pe wọn fi ileeṣẹ Akinpẹlu gba owo lọwọ awọn tọwọ tẹ ni Holland.

Mba waa ni awọn afurasi naa yoo foju bale-ẹjọ laipẹ lati sọ nnkan ti wọn mọ nipa ẹsun nla naa.

Leave a Reply