Badagry ni mo maa n gbe ẹgboogi oloro gba, igba akọkọ ti mo gba Abuja ni wọn mu mu yii-Eze

Faith Adebọla, Eko

Niṣe ni ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji yii, Okey Eze, n ge ika abamọ jẹ lakolo awọn ẹṣọ NDLEA ti wọn mu un l’Abuja l’Ọjọruu, Wẹsidee yii. Egboogi oloro olowo nla ni wọn lo fẹẹ gbe sọda lọọ ilu oyinbo, lokunrin naa ba ni latọjọ toun ti wa lẹnu iṣẹ buruku yii, wọn o mu oun ri, igba akọkọ toun paarọ ọna ni wọn mu oun yii.

Alukoro ileeṣẹ ijọba to n gbogun ti gbigbe, lilo ati ṣiṣe okoowo ẹgboogi oloro nilẹ wa, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, lo fi ọrọ yii ṣọwọ s’ALAROYE lọri ẹrọ ayelujara, o ni ọkan lara awọn ero to ba ọkọ baaluu Ethiopia kan de lafurasi ọdaran ọhun i ṣe. Lati orileede Bamako ni baaluu naa ti gbera, o gba Addis-Ababa kọja si Abuja, olu-ilu wa, bawọn ero inu rẹ si ṣe sọkalẹ ni wọn ti n ṣayewo ara wọn ati ẹru wọn, bẹẹ lẹrọ atanilolobo ti wọn fi ṣayẹwo ẹni to ba gbe ẹru ofin bẹrẹ si i han ganranran, eyi lo jẹ ki wọn mọ pe Eze lẹbọ lẹru.

Nigba ti wọn ṣayẹwo ẹru ẹ, aṣiri tu, ẹgboogi olori to tẹwọn to kilogiraamu mẹjọ (7.70 kilogramme) ni ọja ofin tafurasi ọdaran naa fi ha para kaakiri awọn baagi arinrin-ajo to n gbe bọ, ni wọn ba fi pampẹ ofin mu un.

Wọn lọkunrin naa jẹwọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe iṣẹ awọn to n lẹ taisi (tiles) mọ ilẹ ile loun kọ, idi iṣẹ naa loun wa tẹnikan fi ja oun si ọna ti egboogi oloro yii, lati ọdun 2019 loun ti n ṣowo naa. Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Oji-River, nipinlẹ Enugu, yii sọ pe ilu Eko loun n gbe, agbegbe Badagry loun maa n gbe egboogi oloro oun gba sọda tẹlẹ, ibẹ loun maa n ba lọ siluu Bamako, orileede Mali toun n gbe, ati pe ẹgbọn oun ti wọn pe oun pe ara rẹ ko ya lo jẹ koun maa sare bọ nile, ẹnikan lo si gbe egboogi oloro yii foun ni Addis Ababa, lorileede Ethiopia, pe koun ta a toun ba de Naijiria, lai mọ pe okun maa gbe aparo oun bayii.

Wọn ni idi egboogi to fi lailọọnu di kulubu kulubu jẹ ọtalelọọọdunrun din mẹwaa (350), iye owo rẹ si le ni biliọnu meji naira (N2.3b) ti wọn ba ta a tan.

Ṣa, iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ Eze yii, lẹyin iwadii lo maa balẹ sile-ẹjọ.

Leave a Reply