Faith Adebọla, Eko
Bi ọpa naa ṣe rin lati Abẹokuta de Badagry, nipinlẹ Eko ko ti i ye ẹnikan, ṣugbọn iroyin ayọ lo jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa Eko lawọn ti ri ọpa aṣẹ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun tawọn janduku kan ji gbe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Alukoro ọlọpaa Eko, Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi, lo fọrọ yii to awọn oniroyin leti lọjọ Ẹti, Furaidee yii, pe ọna Badagry, nipinlẹ Eko, lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti gba a, o si ti wa lọfiisi CP Hakeem Odumosu, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, n’Ikẹja bayii.
Olumuyiwa sọ pe iwadii ṣi n tẹ siwaju lati mọ bi ọpa naa ṣe fo lati ipinlẹ Ogun de Eko, ṣugbọn o ni ileeṣẹ ọlọpaa maa ri okodoro iṣẹlẹ naa.
Nigba tawọn akọroyin bi i leere boya wọn ti ri awọn afurasi kan mu lori ọrọ yii, o ni ọrọ to gbẹgẹ ni, oun ko fẹẹ sọ ohun to le ṣakoba fun iṣẹ iwadii to n lọ lọwọ, ṣugbọn bọrọ ṣe jẹ lawọn yoo jẹ karaalu mọ.
Tẹ o ba gbagbe, oru Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni wọn lawọn janduku kan gba oke-aja wọle, ti wọn wọ ipinlẹ Ogun, l’Oke-Mọsan, ti wọn si ji ọpa aṣẹ (maze) wọn sa lọ.