Bamiṣe: Andrew fa aṣọ mi ya, atẹyin lo ti fipa ba mi lo pọ ninu ọkọ BRT-Ẹlẹrii

Faith Adebọla, Eko

Abilekọ Nneka Odezulu, ọkan ninu awọn ẹlẹrii to fẹsun kan Ọgbẹni Andrew Ominikoron, awakọ BRT to n jẹjọ ifipabanilopọ ati ipaniyan l’Ekoo, ti ṣalaye nile-ẹjọ pe inu bọọsi BRT ni afurasi ọdaran naa ti fipa ba oun sun lalẹ ọjọ to gbe oun, o lo fa aṣọ oun ya, atẹyin lo si ti ko ibasun tipatipa foun.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un yii, ni obinrin naa tu pẹrẹpẹrẹ iṣẹlẹ ọhun lasiko ti igbẹjọ n tẹsiwaju lori awọn ẹsun ti wọn fi kan afurasi ọdaran naa, nile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko to fikalẹ si ọgba Tafawa Balewa, l’Erekuṣu Eko. Onidaajọ Sherifat Ṣonaike lo n gbọ ẹjọ naa.
Ninu alaye ti Kọmiṣanna feto idajọ, Amofin Moyọsọrẹ Onigbanjo, to ṣoju fun olupẹjọ, ṣe, o ni Ọgbẹni Andrew gba Abilekọ to fipa ba sun naa leti leralera, o tun fun un lọrun pinpin debi to fi jẹ tipatipa niyẹn fi n mi, asiko naa lo si fa aṣọ rẹ ya, to fipa ba a laṣepọ.
Nigba ti wọn pe Nneka sinu koto igbẹjọ lati ṣalaye bọrọ ṣe jẹ, eyi ni alaye to ṣe:
“Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni mi, mo ti bimọ, mo n ba wọn taja nileetaja kan lagbegbe Lẹkki ni, ibẹ ni mo ti n ṣiṣẹ.
“Lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 to kọja, lẹyin ti mo ti ṣiwọ iṣẹ, ti mo n dari rele ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ, mo lọ si ibudokọ Alesh Hotel, nibi ta a ti maa n wọ ọkọ BRT. Mo lọọ ba dẹrẹba ọkọ BRT yii lati bi i leere boya o maa duro fun mi ni ibudokọ to sun mọ ile mi ni Jakande Estate, o si dahun pe oun maa duro fun mi, ni mo ba wọle, mo lọọ jokoo.
“Lẹyin naa lọkunrin kan tun de, o beere lọwọ dẹrẹba yii boya o maa gba Oṣodi, ni wọn ba bẹrẹ si i jiyan lori owo mọto, ko pẹ lẹyin eyi, ọkunrin naa ba tirẹ lọ.
“Nigba ti mo wọle, ina inu ọkọ naa wa ni titan, ṣugbọn nigba ta a fi maa de adugbo Lẹkki Conservation, lọna marosẹ Lẹkki si Ajah, o duro sẹgbẹẹ ọna, o mu oogun kan jade, o lo o, ṣugbọn mi o fura, tori mo ro pe o kan lo oogun lasan ni.
“Nigba to ya, o ni ki lo de ti mo lọọ da nikan jokoo sẹyin ọkọ, pe ki n waa jokoo sitosi oun lapa iwaju, mo si ṣe bẹẹ. O beere orukọ mi, ọjọ-ori mi, ibi ti mo n gbe, ẹni ti mo n ba gbe atawọn ibeere mi-in. Bo ṣe n ba mi sọrọ lọwọ, o pe awọn meji kan lori aago ẹ, o ba wọn sọrọ, mi o gbọ ọrọ wọn daadaa tori lowe-lowe lo sọrọ. Lo ba tun bẹrẹ si i ba mi sọrọ, o ni ki n jẹ ka lọọ paaki ọkọ sibi kan ka le raaye sọrọ daadaa. Mo fesi pe, ‘ẹ jọọ sa, ibiiṣẹ ni mo ti n bọ, o ti rẹ mi, mo dẹ ṣi maa lọọ mu ọmọ mi lọdọ awọn alagbatọ to maa n wa lẹyin ileewe.’ Bi mo si ṣe n sọrọ yẹn ni mo kiyesi i pe nnkan ọmọkunrin ẹ ti le labẹ aṣọ.
“Mo mu foonu mi nla jade, mo fẹẹ pe ẹnikan ki n si dọgbọn ya fidio nnkan to n ṣẹlẹ, ṣugbọn o ti ri mi, lo ba bi mi pe kin ni mo fẹẹ ṣe yẹn, ta ni mo fẹẹ pe lori aago. Niṣe lo fo dide lori ijokoo awakọ to wa, o si fipa gba foonu naa lọwọ mi. Ki n too mọ ohun to n ṣẹlẹ, o ti fa ọbẹ aṣooro kan yọ si mi, lo ba gan mi lapa, o wọ mi lọ si ijokoo apa ẹyin, o ni ki n bọ aṣọ mi. Mo beere pe ‘kin lo de to fi ni ki n bọṣọ, ṣe a ti mọ ara wa ri tẹlẹ ni?’
“A bẹrẹ si i jiyan, o sọ fun mi pe ṣe ọmọde ni mi ni, o ni ki n bọ gbogbo aṣọ to wa lara mi pata. Lojiji, niṣe lo di igbaju ru mi, lo ba fun mi lọrun pinpin, o loun maa yin mi lọrun pa, agbara kaka ni mo fi n mi.
“Nigba ti mo ri i pe oju ẹ ti yipada kuro ni ti ọmọluabi, niṣe lo da bii ẹhanna, to si tun sọ fun mi pe ki n fọwọ sowọ pọ pẹlu oun tori toun ba pa mi sinu ọkọ naa, ko sẹni to le mọ, ko si sohun to maa ṣẹlẹ, mo juwọ silẹ fun. Lo ba fidi mi gunlẹ sori ijokoo kan lẹyin. Mo fọwọ di ijokoo naa mu lọtun-un losi, mo bẹrẹ si i bẹ ẹ pe ko ṣaanu mi, ko ma ṣe mi leṣe. Ọbẹ ọwọ ẹ lo fi ya aṣọ ọrun mi, o doju mi kọ ijokoo naa, o si ba mi laṣepọ latẹyin. Nigba to ṣe tan, ti ara ẹ walẹ, o pada sori ijokoo dẹrẹba, o si n wa ọkọ lọ.
“Mo sọ fun un pe ko jẹ ki n bọọlẹ, ṣugbọn o ni ṣebi mo ti sọ foun tẹlẹ pe Jakande Estate ni mo n lọ, o loun maa gbe mi debẹ dandan. Nigba ta a debẹ, mo bẹ ẹ pe ko da foonu mi pada fun mi, ko si ṣilẹkun ọkọ fun mi ki n bọọlẹ, asiko yii lo bẹrẹ si i bẹ mi, o ni ki n forijin oun, o loun ti ṣẹ mi fun iwa ọdaran toun hu.
“O ni ki n fun oun ni nọmba akaunti mi, oun maa fun mi lowo, mo ni ko ma ṣeyọnu, pe mi o fẹ owo ẹ, lo ba sọ fun mi pe alagidi ni mi, mi o si fẹ ko tun lọọ huwa aidaa mi-in pẹlu mi, ni mo ba fun un ni nọmba akaunti mi, o si fi ẹgbẹrun mẹta Naira (N3,000) ṣọwọ sibẹ. O tun ni ki n foun ni nọmba foonu mi, mo si fun un, ẹyin naa lo ṣẹṣẹ da foonu to gba lọwọ mi tẹlẹ pada fun mi, o si ṣilẹkun ọkọ ki n le raaye bọ silẹ. Kia ni mo ti fi foonu mi nla ya akọyinsi ọkọ naa ati nọmba ti wọn so mọ ọn.
“Lẹyin wakati diẹ lalẹ ọjọ yẹn, o pe mi lori aago, o ni ki n ma binu soun, ki n fori jin oun, o beere boya mo ti dele, tabi mo ti lọọ mu ọmọ mi lati ileewe, mi o dahun ibeere kankan, mo kan ja a danu lori aago mi ni. O tun pe mi lọjọ keji leralera, ṣugbọn mi o gbe aago ẹ.
“Latọjọ tiṣẹlẹ yẹn ti ṣẹlẹ, ti mo ba fẹẹ wọ ọkọ BRT, ma a kọkọ yọju wo inu ẹ boya oun lo wa a, abi bẹẹ kọ, o ti to ẹẹmẹrin ọtọọtọ ti mo ti pada ri i ni agbegbe too-geeti Chevron yẹn, ṣugbọn ko da mi mọ.”
Bayii ni Abilekọ Odezulu ṣalaye ohun toju ẹ ri lọwọ Ominikoron. Nigba ti wọn bi i lere boya o lọọ fiṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti ni teṣan wọn, o loun o ṣe bẹẹ, latari nnkan tawọn ọlọpaa ti ṣe foun nigba kan toun lọọ fẹjọ sun ni teṣan wọn, o ni niṣe lawọn ọlọpaa maa n bu ẹni to ba mu iru ẹjọ bẹẹ lọ, wọn yoo maa fi tọhun ṣeṣin ni.
Obinrin naa ṣafihan aṣọ rẹ ti afurasi naa fa ya lọjọ iṣẹlẹ ọhun f’adajọ, ṣugbọn agbẹjọro olujẹjọ, Ọgbẹni Abayọmi Ọmọtubora, rọ ile-ẹjọ pe ki wọn ma ṣe gba ẹri naa wọle, o ni iru ẹri bii aṣọ to faya yii ta ko iwe ofin ẹri gbigba wọle nile-ẹjọ to wa ni isọri okoolerugba ati ẹyọ kan (221) ti ọdun 2011 ati isọri kẹrindinlogoji, abala kẹfa, iwe ofin ilẹ wa ti ọdun 1999.
Ṣugbọn Amofin agba Onigbanjo ta ko o, o si rọ ile-ẹjọ pe ki wọn da ẹbẹ agbejọro olujẹjọ nu bii omi iṣanwọ, o ni awawi asan lo n ṣe.
Adajọ Ṣonaike ni ẹbẹ olujẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ rara, o gba ẹri ti ẹlẹrii naa, Abilekọ Odezulu, ṣe, wọle.
Ṣugbọn olujẹjọ naa, Andrew, ni oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn ka soun lẹsẹ. Eyi lo mu ki adajọ sun igbẹjọ to kan siwaju.
Tẹ ẹ o ba gbagbe, olujẹjọ yii ni afurasi ọdaran ti wọn fẹsun kan pe o mọ nipa iku gbigbona ti wọn fi pa ọdọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Oluwabamiṣe Ayanwọla, to wọ ọkọ BRT tafurasi ọdaran yii ṣe dẹrẹba rẹ loṣu Keji, ọdun yii, ki wọn too ri oku rẹ lẹyin ọsẹ kan.

Leave a Reply