Banki apapọ ilẹ wa ti banki alabọọde mejilelogoji pa, wọn ni kawọn to lowo nibẹ waa gbowo wọn pada

Faith Adebọla, Eko

 Ileeṣẹ abanigbofo owo ti wọn ba fipamọ (Nigeria Deposit Insurance Corporation) ti gbawe aṣẹ lọwọ awọn banki alabọọde (microfinance banks) mejilelogoji kaakiri orileede yii, banki apapọ ilẹ wa (Central Bank of Nigeria) si ti fontẹ lu u.

Lori atẹ ayelujara NDIC ti wọn ti kede ọrọ ọhun, wọn ni igbesẹ naa waye latari bawọn banki tọrọ naa kan ko ṣe kun oju oṣuwọn mọ, ti owo idokoowo wọn ko tẹwọn to mọ, ti gbese si ti mu wọn lomi.

Latari eyi, bẹrẹ lati ọjọ kejila, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni awọn banki naa ti kogba sile, wọn si ti gba iwe aṣẹ lọwọ wọn.

Diẹ lara awọn banki tọrọ naa kan nipinlẹ Eko ni Credit Express MFB, n’Isalẹ Eko; King Solomon MFB, n’Ipọnri; Riggs MFB, ni Victoria Island; Billionaire Blue Bricks, Ajah; Susu MFB, ni Yaba, Aguda Titun MFB ati Metro MFB, ni Ọgba, Wealthstream MFB, Apapa.

Omi-in ni Ibogun MFB, Ifọ, nipinlẹ Ogun, awọn to ku si wa lawọn ipinlẹ kaakiri orileede yii.

Nipari ikede naa, wọn ni: Latari eyi, NDIC fẹ ki awọn to fowo pamọ sawọn banki wọnyi tete lọ si adirẹsi tawọn banki naa wa, wọn yoo ba awọn oṣiṣẹ NDIC nibẹ lati ṣayẹwo iwe wọn, ki wọn si ṣeto lati san owo wọn pada, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kejila, titi di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu naa.

Iwadii wa fihan pe eto isanwo pada naa ti bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Leave a Reply