Banki apapọ ilẹ wa yọ awọn alakooso First Bank nipo

Nitori bi wọn ṣe fun ọga agba First Bank, Adeṣọla Adeduntan, ni iwe ‘waa wi tẹnu ẹ, ti wọn si tun papa da a duro lẹnu iṣẹ lai tẹle ilana to yẹ, ileeṣẹ banki apapọ ilẹ wa, CBN, ti da gbogbo awọn ọga agba to n mojuto awọn okoowo First Bank ati banki yii duro.

Ninu awọn adari banki yii tọrọ kan ni Alaga to n mojuto okoowo banki naa, Ọba Otudẹkọ, bakan naa ni Oloye Ibukun Awoṣika ti oun jẹ alaga banki ọhun atawọn mi-in.

Yatọ si eyi, banki apapọ ilẹ wa ni bi bi wọn ṣe yan awọn lọgaalọgaa kan nileeṣẹ naa ko bojumu, bẹẹ lo lodi sofin.

Bakan naa ni ọga agba fun banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, paṣẹ pe ki wọn da ọga agba banki naa ti wọn yọ nipo pada lẹyẹ-o-sọka.

Leave a Reply