Bariga lawọn mẹrin yii ti digunjale, Kaduna lọwọ ti ba wọn

Faith Adebọla, Eko

Mẹrin ni wọn, bọisi ni gbogbo wọn, orukọ wọn ni Pius Eko, ọmọ ọdun mejidinlogun, Daniel Yaki, ọmọ ọdun mọkandinlogun, Junior Micheal ati Samson Yugana tawọn mejeeji jẹ ẹni ọdun mejilelogun, ṣugbọn iṣẹ idigunjale ni wọn gbaju mọ gidi, agbegbe Bariga, nipinlẹ Eko, ni wọn ti n pamọlẹkun kọwọ palaba wọn too segi nipinlẹ Kaduna, nibi ti wọn ti n sa kiri.

SP Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, sọ f’ALAROYE nipa awọn afurasi ọdaran yii pe lọjọ keji, oṣu kọkanla, to kọja yii, lawọn mẹrẹẹrin lọọ digun ja Ọgbẹni Sontochukwu Uzoachukwu lole ni Opopona Iliya, ni Bariga, wọn gba owo rẹpẹtẹ lọwọ rẹ, ni wọn ba sa lọ.

Wọn ni gbara ti kọmisanna ipinlẹ Eko ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun lo ti paṣẹ pe kawọn ọtẹlẹmuyẹ ati awọn to n fi imọ ijinlẹ ṣiṣẹ itọpinpin nileeṣẹ ọlọpaa tete tọpasẹ awọn afurasi wọnyi, ko si pẹ rara ti imọ ẹrọ fi taṣiiri pe wọn ti sa kuro l’Ekoo, wọn ti wa ni Kaduna, lagbegbe ijọba ibilẹ Kachai.

Wọn ni bi wọn ṣe n lọ lawọn agbofinro naa n tọpa wọn lọ, ọwọ si ti kan ọwọ laarin ileeṣẹ ọlọpaa Eko ati ti Kaduna, eyi lo jẹ ki wọn ri wọn mu lọjọ kin-in-ni, oṣu yii, oriṣiiriṣii nnkan ija bii ida, ada, ọbẹ ati ibọn ibilẹ kan ni wọn ka mọ wọn lọwọ, wọn si tun ri lara awọn ẹru ti wọn ji gbe bii kọmputa agbeletan, foonu atawọn nnkan mi-in

Lagọọ ọlọpaa, awọn afurasi naa jẹwọ pe loootọ lawọn n digun jale ni Bariga, ni wọn ba rọ wọn sọkọ pada s’Ekoo ti wọn ti daran, ki wọn le lọọ fimu kata ofin.

Adejọbi ni iwadii ti fẹẹ pari lori ọrọ tiwọn, ile-ẹjọ lọrọ wọn kan.

Leave a Reply