Bata ọrẹ wọn to ko sodo ni wọn fẹẹ ba a mu tomi fi gbe awọn ọmọde meji kan lọ  

Jọkẹ Amọri

Inu odo kan ti wọn n pe ni Rayfield Resort, to wa niluu Jos, nipinlẹ Plateau, ni awọn ọdọmọde meji kan ku si lasiko ti wọn n gbiyanju lati yọ bata ọkan ninu awọn ọrẹ wọn to ko sinu omi naa.

Awọn ọdọmọde ọhun, Micheal Nyam, ọmọ ọdun mẹjọ ati Elijah Solomon, toun jẹ ọmọ ọdun mẹfa ni wọn ba omi lọ nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja yii.

Gyang Pwol tọrọ naa ṣọju rẹ to ṣalaye fun ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, (NAN) sọ pe bata ọrẹ wọn lo bọ somi ti wọn fẹẹ gbiyanju lati ba a mu ti wọn fi bẹ somi, ṣugbọn agbara omi naa le pupọ, bo ṣe ru awọn ọmọde mejeeji lọ niyi, ti wọn ko si ri wọn mọ.

Wọn ti sinku awọn ọmọ mejeeji.

 

Leave a Reply