Adefunkẹ Adebiyi
Ipade ti awọn gomina mọkandinlogun lati ilẹ Hausa ṣe lọjọ Mọnde ọsẹ yii ki i ṣe lasan, niṣe ni wọn fi i koro oju si awọn gomina ẹkun Guusu ti wọn ni apa ọdọ awọn ni aarẹ yoo ti wa ni 2023. Bẹẹ ni wọn si binu si ipinnu awọn gomina Guusu to fẹẹ maa gba owo-ori ọja ta a mọ si VAT, wọn ni ipinnu ti ko lẹsẹ nilẹ ni.
Bi ipade wọn naa ṣe jẹ pajawiri to, to jẹ ojiji ni wọn sare ṣa ara wọn jọ, sibẹ, awọn gomina Oke-Ọya mọkandinlogun naa fẹnu ko, pẹlu Sultan Sokoto, Muhammadu Abubakar kẹta to wa nikalẹ, wọn lawọn ko fara mọ aba awọn gomina Guusu, pe apa ọdọ wọn ni ki aarẹ ti wa ni 2023.
Awọn gomina ilẹ Hausa yii ṣalaye pe bawọn gomina Guusu ṣe sọ pe ọdọ awọn ni aarẹ yoo ti wa ni 2023, lodi si ofin ilẹ Naijiria.
Wọn ni ohun ti ofin sọ ni pe ẹni to ba ni ibo to pọ ju ni yoo di aarẹ, ibi to ti wa ko ni nnkan kan i ṣe, iye ibo to ba ni lo ṣe pataki. Fun idi eyi, wọn ni ipade ẹẹmeji tawọn gomina mẹtadinlogun ẹkun Guusu ṣe lori eyi ko wulo lọdọ tawọn, awọn ko fara mọ ọn.
Ni ti owo-ori ọja (VAT) to ti n ja ran-in-ran-in nilẹ lati ọsẹ meloo kan sẹyin, awọn gomina ilẹ Hausa yii sọ pe aba ti awọn ti Guusu n da, pe awọn lawọn yoo maa gba owo naa ko daa.
Wọn ni ojuṣe ijọba apapọ ni owo-ori ọja, to ba di pe ipinlẹ n gba a, awọn to n ra ọja ni iya rẹ yoo jẹ.
Wọn ni fun apẹẹrẹ, owo-ori ọja yii yatọ sawọn owo ori yooku.
Wọn ni nigba to jẹ awọn onraja lo n san owo yii mọ ọja ti wọn ba ra, to ba lọọ ṣe bẹẹ bọ sọwọ ijọba ipinlẹ, niṣe lawọn ọja yoo wọn buruku, ti inira yoo si ba awọn eeyan to n ra ọja, nitori owo-ori ọja ti wọn ni lati san fun ipinlẹ wọn nikan ṣoṣo yii yoo pọ ju, yatọ si ijọba apapọ to jẹ pe o ni agbara lati gba awọn onraja kalẹ lọwọ inira.
Nipa pe ilu Eko nikan lo n pese ida aadọta (50%) ninu owo-ori ọja ti ijọba apapọ n pin fawọn ilu yooku, awọn gomina yii sọ pe ko sohun to fa a ju pe Eko ni awọn olu ileeṣẹ nla-nla pọ si lọ.
Wọn ni awọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ, awọn banki, awọn ileeṣẹ to n pese nnkan eelo ati bẹẹ bẹẹ lọ to pọ l’Ekoo lo fa a, Eko si n gba owo ti ko yẹ ki wọn maa gba lọwọ wọn ni.
Ṣa, awọn gomina ati ọba ilẹ Hausa yii sọ pe ni tawọn, afi bi ile-ẹjọ to ga ju lọ ba yanju ọrọ ti VAT yii, nitori ọrọ naa ṣi wa nile ẹjọ, awọn ko ni i tẹle aba awọn ti Guusu, ka ma ri i.