Bawọn ọmọ ba wọle, bi korona ba ṣẹlẹ nileewe kan, ohun tijọba Eko yoo ṣe niyi o

Aderounmu Kazeem

Bi awọn ileewe ṣe fẹẹ pada sẹnu iṣẹ, ọkan lara awọn ọga agba nileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ẹkọ l’Ekoo, Arabinrin Abiọla Seriki-Ayẹni, ti sọ pe, ileewe ti iṣẹlẹ arun koronafairọosi ba ti ṣẹlẹ lẹyin tawọn ọmọleewe ba wọle tan, niṣe nijọba yoo ti i pa.

Nibi idanilẹkọọ ọlọjọ meji ti ileeṣẹ naa ṣe fawọn ọga lẹnu iṣẹ olukọni atawọn mi-in tọrọ kan ni Abiọla Seriki-Ayeni ti sọrọ ọhun. Nibẹ lo ti rọ awọn oludari lawọn ileewe lati gbe gbogbo igbesẹ to yẹ ki irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ma baa waye, bẹẹ lo ni ki wọn ṣeto aabo to peye fawọn olukọ, awọn ọmọleewe atawọn oṣiṣẹ mi-in gbogbo lawọn ileewe wọn bi ijọba ti ṣe n gbe igbesẹ bayii lati ṣi awọn ileewe pada nipinlẹ Eko.

O lo ṣe pataki ki awọn alaṣẹ ileewe ti ni in lọkan bayii pe ti iṣẹlẹ koronafairọọsi ba waye, o ti di dandan ki wọn ti irufẹ ileewe bẹẹ na, nitori ko sẹni to ti i le sọ pe arun buruku ọhun ti kasẹ nilẹ tan patapata.

O fi kun un pe, iru ẹ ti ṣẹlẹ lawọn ibi kan lagbaaye to jẹ pe lẹyin ti wọn bẹrẹ iṣẹ pada ni wọn tun kẹfin arun ọhun, ti wọn si ti ileewe wọn loju-ẹsẹ.

 

Leave a Reply