Bayern lu Barca laluwo pẹlu ami-ayo mẹjọ si meji

Iya ami-ayo mẹjọ si meji ki i ṣe nnkan ti ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ilẹ Spain ro pe awọn yoo jẹ lọwọ Bayern Munich ilẹ Germany nibi idije Champions League tọdun yii to n lọ lọwọ, ṣugbọn wọn jẹ iya naa lajẹbanu lalẹ oni.

Agbabọọlu mẹfa lo fi goolu mẹjọ pa Barca lẹkun nipele kuọta faina ti wọn gba lonii, Barca si ju ayo meji wọle, eyi ti ko ran nnkan kan ninu ọrọ to wa nilẹ.

Ifẹsẹwọnsẹ yii ti sun Bayern si ipele sẹmi faina, eyi to kangun si aṣekagba, ẹni to ba si yege ninu Manchester City ati Lyon ti yoo pade lọna ni wọn yoo koju.

Fun Barca, ipade di ọjọ mi-in ọjọ ire.

 

Leave a Reply