Bẹ ẹ ba gbọ orin Wasiu Ayinde lori redio, a jẹ pe ilẹ Hausa ni wọn ti kọ ọ-FIBAN

 Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Kedere lo foju han pe ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ ti wọn n pe ni FIBAN (Freelance And Independent Broadcasters Association Of Nigeria), ko ṣetan lati foriji Oluaye Fuji, Wasiu Ayinde, lori ọrọ MC Murphy, Wọle Ṣorunkẹ, ti wọn lo lu niluu Itori, ti ẹnu iyẹn si bẹ, ti ete rẹ tun wu.

Yeyeluwa Ibiyẹmi Ajadi, ọkan pataki ninu awọn sọrọsọrọ nipinlẹ Ogun lo tubọ fi eyi han lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ kan. Niṣe ni mama naa fi ẹrọ gbohungbohun to mu dani ṣalaye pe ‘’Wasiu ti ṣẹ awa sọrọrọsọ, o ti ṣẹ aye o. A ti fa Wasiu si gbangba aye. Ṣe ni MC Murphy fa ete ẹ yan-an-yan-an-yan-an to fi n han awọn oniroyin. Awa naa yoo waa gbe ikọ alagbara dide lọ sọdọ Alaafin Ọyọ to fun Wasiu ni Mayegun. Mayedaru lo jẹ o, ko jẹ Mayegun. Bẹ ẹ ba gbọ orin Wasiu lori redio, boya nilẹ Hausa’’

One thought on “Bẹ ẹ ba gbọ orin Wasiu Ayinde lori redio, a jẹ pe ilẹ Hausa ni wọn ti kọ ọ-FIBAN

  1. Wasiu kii se omoluabi. Ganranganran re to poju. O so ni igberaga to ko legbe. Ajepe, pro Barrister to n muu niyan. Bi eeyan ba n dagba o ma n ye ogun is ni.Boya yo o kogbon lori eleyi I, too si se .atunse to lóòrìn. Mayegun ni oruko Ifa . Ifa kii mayedaru. Olorun no I Wasiu ko lo ye ko je iru oyè banta banta bayi I. Ki won ro o loye ni.

Leave a Reply

%d bloggers like this: