Bello atọrẹ ẹ n fẹwọn ṣere, waya ina ni wọn n ji tu l’Ekoo

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe dandan ni kawọn afurasi ọdaran meji kan, Tairu Bello, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, ati Bishir Abubakar, ẹni ọdun mejilelọgbọn, kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ, ibi ti wọn ti n fi jiga ati ṣọbiri hu ilẹ lati ji waya ina ka lawọn agbofinro ka wọn mọ, ti wọn fi mu wọn.

 

 

CSP Yinka Ẹgbẹyẹmi to n dari ikọ ọlọpaa RRS (Rapid Response Squad) l’Ekoo, sọ ninu atẹjade to fi sori atẹ ayelujara RRS lori fesibuuku pe nnkan bii aago marun-un fẹẹrẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, lọwọ ba awọn afurasi ọdaran naa.

 

 

Ẹgbẹyẹmi ni awọn kọlọransi ẹda mejeeji ti hu waya ina tijọba ri mọlẹ, waya ti wọn pe ni 240mm cables, wọn ti ka a jọ, roolu mẹta ni wọn ka a si, wọn fẹẹ maa ko o sinu mọto lawọn ọlọpaa RRS yọ si wọn, ni wọn ba fẹẹ sa lọ, ṣugbọn wọn ri wọn mu.

Nigba ti wọn de teṣan pẹlu ẹsibiiti wọn, wọn jẹwọ pe loootọ lawọn n hulẹ lati ji waya tijọba ri mọlẹ ni. Wọn ni agbegbe Idi Iroko, ni Maryland, lawọn ti hu awọn waya naa, Mile-12 lawọn si fẹẹ fi mọto ko o lọ, ibẹ ni wọn lawọn ti maa ta atare ẹ si Owode Onirin, nibi tawọn to fẹẹ ra a lọwọ wọn wa.

 

 

Wọn tun jẹwọ pe ẹẹkeji tawọn maa ṣe’ru iwa ọdaran yii lọwọ ba awọn yii.

Lara awọn irinṣẹ ti wọn fi n ṣiṣẹẹbi wọn tawọn ọlọpaa ka mọ wọn lọwọ ni  ṣọbiri meji, jiga meji, ayun ti wọn fi n rẹ waya kan, haama nla, ṣisuu (chisel), ada ati okun.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ wọn gẹgẹ bi Ẹgbẹyẹmi ṣe wi, wọn yoo si foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply