‘Biṣọọbu’ fipa ba ọmọ rẹ ati t’aladuugbo wọn lo pọ n’Ipaja, lo ba ni wọn purọ m’oun ni

 Jọkẹ Amọri

Niwaju ile-ẹjọ to n ri si ẹsun lilo ọmọ nilokulo ati fifipa ba ọmọde lo pọ  to wa ni Ikẹja, ni wọn gbe baba kan, Felix Okon, ti wọn tun n pe ni ‘Biṣọọbu’, nitori ṣọṣi to da silẹ ninu ile rẹ, to fipa ba ọmọ bibi inu rẹ ati ọmọbinrin mi-in lo pọ lọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ọmọ baba to n gbe Gowon Estate, Ipaja, yii ti ko ju ọmọ ọdun mẹrindinlogun ṣalaye pe lati inu oṣu Kẹjọ, ọdun 2019, ni baba oun ti n fipa ba oun lo pọ nigba tawọn wa ninu ọlude.

O ni lalẹ ọjọ kan ni baba oun pe oun, to si fun oun ni ogogoro mu, lẹyin naa lo tun fun oun ni tọniiki. O ni oju-ẹsẹ ti oun mu kinni naa tan lo bẹrẹ si i rẹ oun. Ọmọbinrin yii ni baba oun ni ki oun sun sori bẹẹdi. Nigba ti oun si ji loru loun ri i pe baba oun ti n ba oun lo pọ.

Ọmọbinrin yii ni oun fẹẹ kigbe, ṣugbọn oun ko le ṣe bẹẹ, bẹẹ loun ko si lagbara lati ti baba naa kuro lori oun. Lẹyin to ba oun lo pọ tan lo ni ki oun lọọ sun sori ẹni to wa ninu yara naa.

Gẹgẹ bi awọn to maa n mojuto alaafia awujọ (Social Wọrker), Arabinrin Rasheedat Sanusi, to waa jẹrii ta ko Felix Okon ṣe sọ, o ni ni kete ti oun gbọ nipa iṣẹlẹ naa loun lọ sileewe ọmọbinrin yii, toun si fọrọ wa a lẹnu wo. Leyin naa loun fi iṣẹlẹ naa to agọ ọlọpaa to wa ni Gowon Estate leti, tawọn agbofinro si lọọ mu un.

Lẹyin naa ni wọn taari ẹjọ naa si ẹka to n mojuto ọrọ awọn ọmọde ni Ikẹja Police Command.

Ọmọbinrin yii ni yatọ si oun, baba oun tun fipa ba ọmọbinrin mi-in to jẹ ọmọde to jẹ ọmọ ṣọṣi baba oun tawọn jọ n gbe ninu ile kan naa lo pọ.

Ṣugbọn agbẹjọrọ fun Okon, Ọgbẹni Maduemezia, ni irọ ni ọmọbinrin naa n pa, o ni baba rẹ ko ṣe ohun to jọ bẹẹ, ati pe ohun ti wọn ni ki ọmọ naa sọ lo n sọ jade lẹnu.

Iwa ti Okon hu ni adajọ lo ni ijiya labẹ ofin iwa ọdaran tipinlẹ Eko, tọdun 2015, pẹlu bo ṣe fipa ba ọmọ to bi ninu ara rẹ lo pọ lọmọ ọdun mẹrinla.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeeji lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun yii. gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, (NAN), ṣe jabọ rẹ.

Leave a Reply