Biṣọọbu Oyedepo yari: Emi o ni i gba abẹrẹ Korona o, mi o ki i ṣe ẹlẹdẹ

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Biṣọọbu David Oyedepo to jẹ olori pata fun ṣọọṣi  Living Faith, ti loun ko ni i gba abẹrẹ ajẹsara Korona tijọba ko wọ Naijiria wa, ti wọn si ti n fun awọn eeyan. Oyedepo loun ki i ṣe ẹlẹdẹ, ki loun fẹẹ fabẹrẹ ṣe.

Lasiko isin ṣọọṣi rẹ kan to pe ni ‘Covenant Hour of Prayer’ ni Biṣọọbu Oyedepo ti sọrọ yii, o si tẹnumọ ọn pe Korona ti da nnkan ru mọ gbogbo agbaye lọwọ, ko ye wọn mọ bi ohun gbogbo ṣe n lọ.

Oyedepo ni, ‘‘Mi o ti i ri iran ti wọn ti n fagidi muuyan lati gba abẹrẹ ajẹsara ri. Ki i ṣe iwa ọmọniyan, o si tun lodi sofin ọmọluabi.  Emi ki i ṣe lọọya, ṣugbọn mi o ro pe o tọna labẹ ofin. O o le wa sile mi ko o lo o fẹẹ gun mi labẹrẹ.

‘‘Fun kin ni? Ṣe mo ranṣẹ pe ọ ni? Wọn o mọ ohun ti wọn n ṣe. Ṣe ẹyin ri kokoro fairọọsi kankan nibi? Nibo lo fẹẹ gba wọ geeti? Ṣo fẹẹ gba inu afẹfẹ wa ni abi bawo?

‘‘Ẹyin ẹ jẹ ki n ri ẹnikan ko loun fẹẹ waa fun mi labẹrẹ kan, bawo lo ti ẹ ṣe fẹẹ ṣe e? Ṣe o maa so mi lọwọ pọ ni abi bawo. Iṣẹ temi ni lati tu aṣiri Eṣu, ki n si sọ fawọn iranṣẹ ẹ pe ki wọn pada lẹyin wa. A ki i ṣẹ ẹlẹdẹ.’’

Pasitọ yii ṣalaye pe abẹrẹ Korona yii lobinrin kan gba ni Kaduna to dọran si i lọrun, o ni iru igbesi aye wo leyi, ati pe ṣe awọn eeyan ti di ẹlẹdẹ to nilo abẹrẹ ni.

Oyedepo sọ pe ile aye ni nnkan daru mọ lọwọ ti wọn n gun abẹre Koro kiri, ijọ Ọlọrun ko daru, o n ṣẹgun lọ ni.

Ohun tawọn eeyan n sọ lori ipinnu Biṣọọbu agba yii ni pe njẹ awọn ọmọ ijọ rẹ naa yoo fẹẹ gba abẹrẹ Koro bayii, nigba to jẹ aṣiwaju wọn ti loun ko ni i gba a, to si jẹ ohun ti aṣiwaju ba ṣe lawọn ọmọlẹyin rẹ naa yoo fẹẹ ṣe.

Leave a Reply