Adefunkẹ Adebiyi
Laipẹ yii ni iroyin jade pe awọn kan ni Naijiria yii lo n ṣatilẹyin fun ikọ aṣekupani nni, Boko Haram, ti kaluku si fẹẹ mọ wọn gẹlẹ. Ṣugbọn Minisita eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami, ti sọ pe ijọba ko le darukọ awọn onigbọwọ Boko Haram lasiko yii, wọn ko si le foju wọn han, nitori bawọn ba ṣe bẹẹ, yoo pa iwadii awọn lara.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an yii, ni Malami sọrọ yii niluu New York, gẹgẹ bi atẹjade to ti ọdọ Agbẹnusọ rẹ, Umar Gwandu, jade ṣe wi.
Malami sọ pe ijọba apapọ n ṣiṣẹ takuntakun lati fiya jẹ awọn ti wọn n ṣatilẹyin fun ikọ apaayan naa, wọn si n gbiyanju gidi lati ṣẹgun idunkooko mọ ni lorilẹ-ede yii.
O fi kun alaye ẹ pe iwadii awọn eeyan to n ran Boko Haram lọwọ naa ti de ibi to lapẹẹrẹ bayii, to ba si to asiko ti ijọba yoo gbe ọrọ jade lori rẹ, wọn yoo fi atẹjade sita.
Minisita eto idajọ naa tẹsiwaju pe ohun to ṣe pataki ju naa ni aabo awọn eeyan ilu, ki wọn si ni ifọkanbalẹ. O ni ṣugbọn asiko ko ti i to bayii lati ṣiṣọ loju eegun awọn ti wọn n ti Boko Haram lẹyin, ko ma lọọ ṣakoba fun ilọsiwaju iwadii tijọba n ṣe.
“ Nipa idunkooko mọ ni ati awọn to n fun wọn lowo lati fi ṣe e, a ti mọ awọn ti wọn ni wọn n kowo fun wọn lati ṣiṣẹ naa, a si ti n di awọn ọna ti wọn n gba kowo fun wọn. Mi o fẹẹ sọ awọn ọrọ kan to le di aṣeyọri ta a n ṣe lori iṣẹlẹ yii lọwọ.”
Bẹẹ ni Malami wi, ṣugbọn o ni gbogbo igbesẹ tijọba apapọ n gbe lo wa ni ibamu pẹlu ofin.
O waa fi kun alaye naa pe Korona ati iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ kootu foṣu meji naa wa lara idi ti awọn onigbọwọ Boko Haram ko ṣe ti i foju bale-ẹjọ.