Bi a ba fẹ idagbasoke ti ko lẹgbẹ, a nilo lati gbe awọn igbesẹ to lagbara -Tinubu

Aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti sọ pe ti a ba fẹ eto idagbasoke to mọyan lori lorileede wa, afikun owo epo yii ṣe pataki, nitori igbesẹ naa yoo mu idagbasoke ati atunṣe nla ba ilẹ wa. Tinubu sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, oṣu yii, lasiko to n ṣepade pẹlu ẹgbẹ ọmọ Naijiria to wa ni orileede China, Nigerians in Diaspora Organization (NIDO),

to si n tun n jabọ ipade to ṣe pẹlu aarẹ orileede naa,
eyi to waye ni China World Hotel.

Ninu atẹjade ti Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Ajuri Ngelale, fọwọ si ni Aarẹ ti sọ pe eeso rere ti yoo mu anfaani nipa ọrọ-aje, eto isuna, nnkan amusagbara eto ọgbin ati bẹẹ bẹẹ lọ wa fun orileede wa ni ipade toun waa ṣe pẹlu Aarẹ ilẹ China yii da le lori. Olori ilẹ wa ṣalaye pe oun yoo mu ayipada gidi ba awọn ohun amayedẹrun nilẹ wa, awọn ohun toun si ri ni orileede China yoo jẹ ṣiṣe silẹ wa naa, to bẹ ti ilẹ Naijiria yoo maa fẹgbẹ kẹgbẹ pẹlu ilẹ China lori eto amayederun.

Ninu ọrọ to sọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria to n gbe ilẹ China lo ti ṣalaye pe awọn atunṣe to n lọ lọwọ lorileede yii ṣe pataki, o si ṣe pọn dandan lati gbe awọn igbesẹ kan to lagbara, eyi ti yoo mu anfaani idagbasoke ba ilẹ wa. Tinubu ni bi a ba fẹ idagbasoke ti ko lẹlẹgbẹ, awọn ohun kan wa ti ijọba gbọdọ ṣe, bo tilẹ jẹ pe o le lagbara diẹ.

Aarẹ ni oun mọ awọn ipenija ti awọn eeyan orileede yii n koju, paapaa ju lọ lori afikun owo epo.

O ni, ‘’Asia ti ko labawọn rara la fẹẹ fi le awọn ọmọ wa lọwọ, ki waa ni anfaani ti yoo jẹ fun wa bi a ko ba le gbe awọn igbesẹ kan to lagbara lati ri i pe eleyii di mimuṣẹ’’.

O fi kun un pe awọn to n ba oun ṣiṣẹ kun oju oṣuwọn, wọn si gbamuṣe, bẹẹ loun ti pinnu lati gbe awọn igbesẹ to le koko fun itẹsiwaju ati idagbasoke orileede Naijiria.

O rọ awọn ọmọ Naijiria to wa lorileede naa lati jẹ aṣoju rere, ki wọn si maa ṣọju orileede Naijiria daadaa pẹlu iwa ọmọluabi.

Leave a Reply