Jọkẹ Amọri
Mẹtala ninu awọn alaga ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun ta a ni nilẹ yii ni wọn ti faake kọri bayii pe bi banki apapọ ilẹ wa ba tun fi le sun ọjọ ti gbigba owo atijọ nilẹ siwaju, awọn ko ni i kopa ninu eto idibo ti yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.
Alaga apapọ ẹgbẹ Action Alliance, to jẹ alaga wọn, Kenneth Udese, lo sọrọ yii di mimọ fawọn oniroyin.
O ṣalaye bayii pe ‘‘Awa alaga mẹtala ninu ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to wa nilẹ yii n fi asiko yii sọ pe a ko ni i nifẹẹ si eto idibo ọdun yii, bẹẹ ni a ko ni i kopa ninu rẹ ti ijọba ba wọgi le eto pipaarọ owo tuntun yii, tabi ti wọn ba sun ọjọ kẹwaa, oṣu Keji yii, ti wọn ni opin yoo de ba pipaarọ owo naa siwaju.
Bakan na ni wọn lu ijọba Buhari lọgọ ẹnu fun igbesẹ akin to gbe lati paarọ owo ilẹ wa mẹta nni, igba Naira, ẹẹdẹgbẹta Naira ati ọgọrun-un kan Naira, bẹẹ ni wọn sọ pe ipinnu naa gbọdọ duro.
Wọn tun bu ẹnu atẹ lu bi awọn gomina ipinlẹ Kaduna, Kogi ati Zamfara ṣe fẹẹ gba kootu lọ lati sun asiko ti wọn yoo paarọ awọn owo atijọ naa da siwaju.
Nigba to n sọrọ nibi ipade naa, nibi ti awọn alaga ẹgbẹ oṣelu, awọn oludije sipo aarẹ, ipo gomina, sẹneeti, ati ileegbimọ aṣofin agba peju si ni wọn ti sọ pe igbesẹ tijọba gbe lori atunṣe owo Naira tuntun yii yoo fun awọn eeyan nigbẹkẹle lori eto idibo ọdun 2023 yii. Wọn ni ti eto idibo naa ba fi waye lai jẹ pe wọn fi ọjọ kun asiko ti wọn ti kede tẹlẹ, eyi yoo fi Aarẹ Buhari han gege bii ẹni to gbe igbeṣẹ nla lori ileri to ṣe fun gbogbo agbaye pe oun yoo ṣe eto idibo to mọyan lori, ti ko si ni eru tabi awuruju kankan ninu.
Udeze fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti n gbọ ọ labẹlẹ, bẹẹ ni awọn owuyẹ kan ti fi to awọn leti pe awọn kan ti n gbero lati da wahala, idaluru ati aibalẹ ọkan silẹ debii pe wọn yoo fi le fi sun ọjọ ti eto idibo yoo waye siwaju, tabi ki wọn mu ki iṣejọba Buhari wa sopin lojiji. ‘Wọn ti pe wa si iru nnkan yii, ọpọlọpọ ileri lọlọkan-o-jọkan ni wọn ti ṣe fun wa lati le mu erongba wọn ṣẹ, ṣugbọn awa wo o pe orileede Naijiria ṣe pataki si wa ju ohunkohun ti wọn le ṣeleri fun wa lọ’’.
O ni awọn gomina APC kan, ninu eyi ti awọn gomina ilẹ Yoruba ati ilẹ Hausa pẹlu ilẹ Ibo wa ni wọn n gbomi wahala naa kana. O waa rọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lati fura si awọn eeyan naa.
Bakan naa ni wọn waa rọ awọn adari banki lati ri i pe wọn ṣe ohun to yẹ lati ri i pe awọn araalu ri owo gba.