‘Bi Buhari ṣe ni ki ọga ọlọpaa patapata maa baṣẹ lọ tapa sofin’

Faith Adebọla

Awọn amofin agba meji kan nilẹ wa, Ẹbun-Olu Adegoruwa ati Mike Ozekhome, ti kede pe bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe paṣẹ pe ki Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa, Mohammed Adamu, maa ba iṣẹ rẹ lọ fun oṣu mẹta si i, ko bofin mu rara, wọn ni aṣẹ ti ko le fidi mulẹ ni, afi ki Buhari tete rifaasi (reverse) ara rẹ lori ọrọ naa.

Amofin agba Adegboruwa, to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, lo kọkọ sọrọ ọhun laṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ninu atẹjade kan. O ni igbesẹ to ta ko ofin nigbesẹ ti Aarẹ Buhari gbe ọhun, tori loju ofin, orileede yii ko ti i ni oga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa titi di ba a ṣe n sọ yii.

Adegboruwa ni ọjọ keji, oṣu keji, ni Mohammed Adamu ti fẹyinti nipo ọhun, o si ti kuro lara awọn ọlọpaa ilẹ wa lọjọ naa, ohun ti ofin si sọ ni pe ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa kan ba ti fẹyinti latari pe onitọhun ti sin ijọba fun ọdun marundinlogoji ti ofin sọ, wọn o tun gbọdọ sọ pe kiru ẹni bẹẹ tun maa ba iṣẹ niṣo mọ.

O ni isọri okoolerugba o din marun-un (215) apa ki-in-ni iwe ofin Naijiria, ati isọri keje apa kẹta iwe ofin ileeṣẹ ọlọpaa ti ọdun 2020 sọ pe ẹni ti wọn maa yan lati di ipo ọga agba pata awọn ọlọpaa mu gbọdọ jẹ ẹni to ṣi wa ninu iṣẹ ọlọpaa, ki i ṣe ẹni to ti fẹyinti. O ni aṣẹ Aarẹ Buhari ko debi pe ki o yan ẹni to ti fẹyinti lati dipo naa mu tabi ko maa baṣẹ lọ.

Yatọ seyi, o ni Aarẹ Buhari ko le da nikan yan ẹnikan sipo ọga agba ọlọpaa, ko si le fi ami fa-a-gun si i fẹnikan, lai kọkọ fọrọ lọ ajọ to n dari ileeṣẹ ọlọpaa (Nigerian Police Council), awọn ni wọn gbọdọ kọkọ jokoo, ki wọn yiiri ọrọ naa wo, ki wọn si fọwọ si i, ki Aarẹ too faṣẹ si i, ajọ naa ko si ti i jokoo debii pe wọn yoo jiroro tabi fọwọ si iyansipo kankan.

Niṣe ni Ajafẹtọọ ọmọniyan mi-in, Mike Ozekhome, ni tirẹ la ọrọ mọlẹ, o ni o lodi sofin, aṣiṣe nla gbaa ni, igbesẹ ti Aarẹ gbe naa ko bofin mu, ko tọna, aṣilo agbara ni pẹlu.

O ni ko sẹni ti ko mọ pe ọjọ ki-in-ni, oṣu keji yii, ni Adamu maa fẹyinti, gbogbo aye lo mọ pe ọdun 1961 ni wọn bi i, gbogbo aye lo si mọ pe ọdun marundinlogoji sẹyin ko ti wọṣẹ ọlọpaa.

Ọrọ yii o ruju rara, kedere ni isọri kejidinlogun, abala kẹjọ, iwe ofin ileeṣẹ ọlọpaa tọdun 2020, sọ pe ti ọga agba ileeṣẹ naa ba ti lo ọdun marundinlogoji lẹnu iṣẹ, tabi to ba ti pe ẹni ọdun marundinlaaadọrin lọjọ ori, o gbọdọ fẹyinti.

Mike waa beere pe, ki lo de tawọn to n ṣiṣẹ pẹlu Aarẹ ki i gba a nimọran bo ṣe yẹ, ki ni wọn n wo ti Aarẹ fi n maa n ṣi ẹsẹ gbe lori ofin to ṣe kedere bii iwọnyi lọpọ igba, iṣẹ kin ni wọn n ṣe gan-an, abi wọn o mọ pe nnkan idojuti lo jẹ ti Aarẹ ba n kọsẹ lori ofin leralera ni?

Ṣe ṣaaju ni Aarẹ Buhari ti fọwọ si i, to si paṣẹ pe ki Mohammed Adamu to ti fẹyinti lọjọ ki-in-ni, oṣu keji, bii ọga agba pata fun ilẹ wa, maa ba iṣẹ rẹ lọ fun oṣu mẹta mi-in. Ṣugbọn awọn agbẹjọro mejeeji ti leri pe awọn n reti ki Aarẹ tete ṣatunṣe lori ọrọ yii lẹsẹkẹsẹ, aijẹ bẹẹ, awọn maa pade ẹ nileejọ laipẹ.

Leave a Reply