Bi ẹ ba fẹẹ dupo oṣelu ni 2023, ẹ tete fijọba mi silẹ bayii- Gomina Dapọ Abiọdun

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu kejila, ọdun 2021 yii ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, kilọ fawọn to yan sipo ninu ijọba rẹ pe bi ẹnikẹni ninu wọn ba ni i lọkan lati dije dupo kankan ni 2023, ki tọhun tete fijọba oun silẹ  bayii. Tabi o pẹ ju, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022.

 

Ninu atẹjade to ti ọfiisi Akọwe iroyin gomina wa lọjọ Iṣẹgun naa, iyẹn Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, ni gomina ti sọrọ yii di mimọ.

 

Atẹjade naa ṣalaye pe ijọba Gomina Dapọ Abiọdun ko fẹ ohun ti yoo dena igbega ipinlẹ Ogun to gbe dani, aja awọn oloṣelu to ba fẹẹ dupo mi-in yii ko si le roro titi ko ṣọ ojule meji lẹẹkan ṣoṣo.

Iyẹn lo ṣe ṣe pataki pe bi wọn ba fẹẹ dupo oṣelu, ki wọn fi eyi ti wọn n ṣe lọwọ yii silẹ, nitori iranṣẹ kan ko le sin baba meji lẹẹkan ṣoṣo.

 

Gomina tẹsiwaju pe ki i ṣe ẹṣẹ lati fẹẹ kopa ninu oṣelu, ṣugbọn ki ọkan ma ba di ikeji lọwọ ni ikilọ yii ṣe waye.

Bi ẹnikẹni ko ba fẹẹ tẹsiwaju mọ nitori ati dije dupo, aaye wa lati ṣe bẹẹ lasiko yii titi di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kin-in-ni ọdun 2022 ni ikede naa wi.

Leave a Reply