Bi ẹnikẹni ba kọlu yin, ẹyin naa ẹ kọlu wọn – Ọga ọlọpaa patapata

Nitori bi awọn janduku kan ṣe pa awọn ọlọpaa nipakupa lasiko rogbodiyan SARS, Ọga ọlọpaa orilẹ-ede yii, Mohammed Adamu, ti paṣẹ fawọn agbofinro pe ki awọn naa kọlu wọn lati daabo bo ara wọn lọwọ awọn tọọgi to ba doju ija kọ wọn.

Adamu sọrọ yii nigba to lọọ ṣabẹwo lori eto aabo kaakiri ilu Abuja. O ni, “Araalu ni ẹyin ọlọpaa naa, bẹẹ lẹyin naa ni ẹtọ, fun idi eyi, ko yẹ ki ẹnikẹni fi ẹtọ tiyin naa du yin.”

Ọga ọlọpaa ti fun awọn ọlọpaa laṣẹ lati koju ija sẹnikẹni to ba kọlu wọn, nitori awọn ọlọpaa naa lẹtọọ daadaa, ko si yẹ ki tọọgi tabi janduku kankan maa fi ẹmi tiwọn naa wewu.

O fi kun un pe ọrọ ti oun sọ yii, oun fẹẹ fi da araalu loju pe awọn ọlọpaa naa lẹtọọ labẹ ofin, awọn naa  si gbọdọ daabo bo ara wọn daadaa.

Bakan naa lo sọ pe, “Ti a ba ri janduku kan to kọlu yin, gbogbo ọna ni ki ẹyin naa gba fi daabo bo ara yin, paapaa ti ko ba si ọna abayọ mọ rara.”

Leave a Reply