Bi ijọba Tinubu ṣe ti olori ajọ EFCC mọle lọwọ oṣelu ninu -Ọlajẹngbesi

Monisọla Saka

Lọọya kan to tun jẹ ajafẹtoọ ọmọniyan lorilẹ-ede yii, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, ti sọko ọrọ si Aarẹ ilẹ wa, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ati ijọba rẹ, lori bi wọn ṣe ti ọga agba ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crime Commission (EFCC), Ọgbẹni Abdulrasheed Bawa, mọle lai foju ẹ bale-ẹjọ.

O ni iwa ti ko bofin mu, to si tabuku orilẹ-ede Naijiria ni igbesẹ ti ijọba gbe pẹlu bi wọn ko ṣe wọ ọ lọ sile-ẹjọ lati fẹsun kan an.

Ọlajẹngbesi ti i ṣe ọkan lara awọn alakooso ileeṣẹ imọ ofin kan ti wọn n pe ni Law Corridor, niluu Abuja, ni loju awọn orilẹ-ede agbaye, nitori ija ti Bawa n ja ta ko iwa ibajẹ ni wọn ṣe fẹẹ gbogun ti i.

O sọrọ siwaju si i pe ọkunrin ti wọn ti ti mọle lati bii ọsẹ mẹta sẹyin lai jẹ pe wọn wọ ọ lọ si kootu pẹlu oniruuru ẹri lọrun ẹ mu ifura dani, ati pe nnkan tọrọ naa tumọ si bayii ni pe wọn ti tọwọ oṣelu bọ ọ.

Ninu atẹjade to to fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun yii, lo ti sọ pe awọn eeyan kan saara si Aarẹ Tinubu fun bi wọn ṣe fofin de Bawa lọsẹ mẹta sẹyin bayii, itumọ to si ni sawọn eeyan ni pe ko sẹni ti yoo mu iwa palapala kan jẹ.

“Amọ ṣa, ọsẹ mẹta ti wọn ti ti i mọle bayii lọna ti ko bofin ku diẹ kaato. Bawọn ọlọpaa inu, iyẹn DSS, si ṣe ti i mọle yii ti n mu ifura lọwọ pe wọn ti ti toṣelu bọ ọ pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn ileeṣẹ bii EFCC, ICPC ati ileeṣẹ ọlọpaa Ilẹ Naijiria, ni wọn lewaju ninu gbigbogun ti iwa ibajẹ, paapaa ju lọ ajọ EFCC, ti wọn si ti ṣe gudugudu meje nileeṣẹ yii. Bi wọn ṣe ti ẹni to jẹ olori fun wọn tẹlẹ mọle yii yoo mu kawọn orilẹ-ede toju bọ ọrọ naa, eyi yoo si ṣafihan ilẹ Naijiria bii orilẹ-ede ti ko daa”.

O tẹsiwaju pe oun ko sọ eleyii lati gbe ọga EFCC tọwọ ati ẹsẹ rẹ ko mọ yii nija, nitori ko sẹni to kọja ofin, ṣugbọn ohun ti ofin wi ni ki wọn tẹle, ki wọn ma si ṣe ti ojuṣaaju bọ ọ.

O ke si Tinubu pe ọrọ to wa nilẹ ọhun pe fun ọpọlọpọ iwadii finnifinni, kawọn aye ma baa pada waa re kuro lori Bawa, ki wọn maa waa bu Tinubu pada.

Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun yii, nijọba apapọ paṣẹ pe ki Bawa dawọ iṣẹ duro, latigba naa lo si ti dero atimọle awọn DSS.

Leave a Reply