Bi ipinlẹ kọọkan ba ṣe n pawo wọle lo yẹ ki ijọba apapọ maa fun wọn lowo-Akeredolu

Faith Adebọla

 Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo ti pe fun wiwọgi le ileegbimọ aṣofin agba, iyẹn tawọn ṣenetọ, o ni aṣeju ni irun aya, ileegbimọ aṣofin kan ti to fun ijọba apapọ ilẹ wa, gẹgẹ bo ṣe wa lawọn ipinlẹ.

Nigba to n sọrọ l’Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, nibi apero ita gbangba tawọn aṣofin gbe kalẹ lati gbọ ero araalu lori atunyẹwo ati atunṣe ti wọn fẹẹ ṣe si iwe ofin ilẹ wa, ni gomina la ọrọ ọhun mọlẹ.

Akeredolu, ẹni ti igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa, ṣoju fun, sọ pe oniruuru ẹka ati ajọ tijọba apapọ gbooro de ti pọ ju, o si ti fẹ ju, niṣe ni gbigbooro naa n gbọn ijọba lowo lọ.

O ni: “A ni lati wọgi le ileegbimọ aṣofin agba (senate) ni. Ileegbimọ aṣoju-ṣofin paapaa gbọdọ mọ niwọn. Ti aṣoju bii mẹrin lati ẹkun kọọkan ti to. Ko gbọdọ si owo ajẹmọnu kan ti wọn maa san fun wọn lai jẹ pe igbimọ to n ri si pipawo wọle ati pipin in (Revenue Mobilization and Allocation Committee) mọ si i, ati ni pataki, kawọn eeyan ti wọn lawọn n ṣoju fun mọ si i pẹlu. Eto owo-oṣu tawọn oṣiṣẹ ọba fi n gbowo lo yẹ kawọn aṣofin naa maa fi gbowo wọn, ko yẹ kowo kan wa ti wọn n gba ni bonkẹlẹ.”

Akeredolu tẹsiwaju, o ni: “Ijọba ipinlẹ Ondo ti fi ero rẹ han nipa atunyẹwo ofin yii. Awọn iṣẹ akanṣẹ tijọba apapọ wa maya ti pọ ju, a ni lati din in ku. Ko yẹ kijọba apapọ ati ipinlẹ maa ba ara awọn dije iṣẹ akanṣe faraalu. Iṣẹ to yẹ kijọba apapọ gbaju mọ ni bi wọn ṣe maa ṣe kokaari awọn igbokegbodo ijọba, ki wọn si yee da si ọrọ awọn ipele iṣakoso to ku. Ko yẹ ko jẹ ijọba apapọ lo maa maa ṣofin lori awọn ọrọ pẹẹpẹẹpẹẹ nipinlẹ kaluku. Didin agbara iṣakoso ku ati pipin agbara ijọba lọna to wa deede gbọdọ tete waye ta o ba fẹ ki gbogbo idarudapọ ati ọrọ-aje to n ṣojojo yii doju de.

“Bi ijọba ipinlẹ kan ba ṣe pawo wọle to lo ṣe yẹ ki wọn pinwo fun un to. Ko si boju mu rara bo ṣe jẹ pe ijọba apapọ lo n paṣẹ lori awọn ijọba ibilẹ.

“A fẹ ki wọn ṣofin nipa idasilẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ. Eyi to jẹ pe ẹni kan ṣoṣo lo n paṣẹ awọn ọlọpaa Naijiria teeyan to ju miliọnu igba (200) wa, pẹlu awọn iyatọ ni ti ede, ẹya, iran ati aṣa yii, ko bọ si i rara. Iṣẹ ọlọpaa yatọ si ti oṣelu, tori ọrọ nipa aabo araalu ati dukia la n sọ nipa ẹ yii. Awọn ọlọpaa gbọdọ mọ agbegbe ti wọn feẹ maa sọ dunju. Olori iṣẹ ijọba ati toṣelu ni lati pese aabo ẹmi ati dukia faraalu, gbogbo ọna si la gbọdọ gba lati mu ki eyi ṣee ṣe.”

Leave a Reply