Bi irọ ba lọ logun ọdun…

Nigba ti rogbodiyan yii rọlẹ diẹ lọjọ Sannde, ti mo n wa nnkan ti mo le fi sọ ọkan mi to ga soke kalẹ, lara awọn orin ti mo fẹran lati maa gbọ ni mo gbe si i. Awo orin ti mo gbe si i ni ti Ayinla Ọmọwura, akọle rẹ si ni ‘Ebi ki i pa’gun d’ọjọ alẹ.’  Ilu Adewọle Onilu-Ọla ni wọn fi bẹrẹ awo yii, ohun to si lu sibẹ ni pe: ‘Orimadegun ọkọ Silifa, L’ọjo kan lotitọ o ba a, b’irọ n lọ l’ogun ọdun, l’ọjọ kan lotitọ o ba a!’ Nigba ti mo si ti gbọ ilu naa, ọkan mi walẹ pẹsẹ. Mo ronu ara mi wo pe n ko ṣebajẹ, n ko ṣe aburu, n ko dalẹ Yoruba. Gbogbo eyi ti mo si n wi, ododo ọrọ ni. Bo ti ri ni mo n sọ. Bi ko si ye awọn eeyan mi-in loni-in, o n bọ waa ye wọn lọla, nitori bi irọ ba lọ logun ọdun loootọ, ọjọ kan bayii lootọ yoo ba a. Ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii fi han bẹẹ, o fi iyatọ han larin emi atawọn oloṣelu apurọjẹun pẹlu awọn ọmọlẹyin wọn.

Ọlọrun lo yọ Yoruba lọsẹ to kọja yii o. Ọlọrun lo yọ Naijiria paapaa. Ṣugbọn yiyọ t’Ọlọrun yọ Yoruba pọ ju eyi to fi yọ Naijiria lọ. Bo ba ṣe pe nigba ti wọn n fa ọrọ yii, ohun ti awọn Hausa ti wọn wa laarin wa fẹẹ ṣe ni Fagba, Ageege, ṣee ṣe fun wọn ni, eyi ti a n wi yii kọ la ba maa wi rara. Bo ba ṣe pe wọn ribi dana sun awọn ile ti wọn fẹẹ sun loru, ti wọn ribi pa awọn ọmọ Yoruba, nitori ati ko wọn lẹru, tawọn Yoruba naa gbẹsan, ti Mọla bii meji, mẹta tabi ju bẹẹ lọ ba ku, ọrọ naa iba ran kari Eko laarin iṣẹju diẹ, aa si kari ilẹ Yoruba pata ki ilẹ ọjọ naa too ṣu. Nigba naa lẹ oo mọ bawọn Hausa wọnyi ti yi wa ka to, ẹ ba si mọ aburu tawọn oloṣelu ilẹ Yoruba ṣe. Nigba naa ni ọpọ aa mọ idi ariwo ti mo n pa lojoojumọ, ati idi ti mo fi n sọrọ sawọn oloṣelu wa. Ṣugbọn ki Ọlọrun ma jẹ ki awọn pupọ ninu wa jẹ adọrun-mootọ.

Gbogbo awa ti a ba n gbadura fun ilẹ Yoruba, ka tubọ mura si i o. Ẹyin ti ẹ ba n gbadura fun Naijiria naa, ẹ tete yaa tẹra mọ ọn. Ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii ki i ṣe apẹẹrẹ rere, apẹẹrẹ buruku gbaa ni. Aya mi n ja paapaa. Idi ijaya mi ni pe bo ṣe ri yii, ohun to ṣẹlẹ yii ko tun ni i pẹẹ ṣẹlẹ, bo ba si ṣẹlẹ lẹẹkeji yii, o maa le ju takọkọ lọ, paapaa bo ba jẹ bi awọn oloṣẹlu atawọn jẹgudujẹra aarin wa ṣe n ṣe yii naa ni wọn n  se. A ti tẹ́, awọn oloṣelu aarin wa ti tẹ́ wa. Wọn ti sọ wa deeyan yẹpẹrẹ laarin awọn ẹya to ku ni Naijiria, ki Ọlọrun da iyi ati apọnle Yoruba pada ni. Gbogbo ohun ti a ba gbe dani lasiko yii lo n fọ tuẹ, nigba ti ko si iṣọkan ẹyọ kan bayii laarin wa. Bawọn kan ba n gbe e siwaju laaarọ, bi yoo ba fi dọsan, awọn mi-in aa ti gbe e pada sẹyin, wọn aa si maa kigbe lori redio ati tẹlifiṣan fatafata pe ohun to dara ju lọ lawọn n ṣe. Bẹe lawọn kan aa dide ti wọn aa maa gbeja wọn lẹsẹkẹsẹ.

Awọn yii gan-an ni iṣoro ti Yoruba ni. Iyẹn awọn alaimọkan to pọ ju lọ laarin wa. Awọn ti wọn n gbeja awọn oloselu ti wọn ko mọ ile wọn, ti wọn ko si mọ ọna wọn, ti wọn ko si mọ aṣiri wọn ati iru eeyan ti wọn jẹ gan-an. Paripari rẹ ni pe awọn oloṣelu yii n ba tiwọn jẹ ni o: wọn ko ri tiwọn ro, gbogbo owo ti wọn iba si fi ṣoriire lawọn n ko fun ara wọn ati fawọn ọmọ wọn. Ṣugbọn awọn ti ko ni arojinlẹ  yii ni wọn yoo dide, ti wọn aa bẹrẹ ariwo pe oloṣelu yii ni oloore awọn, oun lawọn fẹran ju, ẹnikẹni to ba n ba a ja, ọta awọn ni. Kaluku ti n ri i, ootọ ti n fara han, ẹru to si n ba mi ju ni pe nigba ti ootọ yii ba jade gboo, ko ma jẹ ọpọ eeyan lo maa ba kinni naa lọ. Naijiria ti de ori ọgẹgẹrẹ bayii, awon eeyan kan si n gbiyanju lati re e si koto, bi wọn ba ṣe bẹẹ, bawo ni ti Yoruba yoo ti ri o.

Bi ẹ ba wo ohun to ṣẹlẹ wẹrẹ yii, ẹ oo ri i pe ilẹ Yoruba ni ifarapa naa pọ si ju lọ. Nibi yii ni wọn ti yinbon fawọn ọmọ wa; nibi yii ni awọn ileeṣẹ ati dukia wa ti bajẹ ju lọ. Gẹgẹ bi awọn oloṣelu ti maa n ṣe, kia ni wọn ti n wa ẹni ti wọn aa di ẹru ọrọ naa le lori. Awọn ti wọn jẹ APC n sọ pe awọn PDP lo wa nidii ẹ; bẹe lawon ti wọn n ṣe PDP n sọ pe awọn APC lo ko awọn ọdọ yii jade. Ijọba ni awọn ọta awọn ni, wọn fẹẹ sọrọ naa di ti ẹleyamẹya, ṣugbọn wọn ri i pe ko si eyi to ṣee ṣe ninu gbogbo ete wọn. Awon eeyan ya wọlu, wọn si bẹrẹ si i fi ile awọn oloṣelu ṣe ọna, wọn n lọọ ko ẹru ti wọn ko pamọ: eyi to jẹ ti ilu ati eyi to jẹ tara wọn. O daju pe bi oloṣẹlu mi-in ba yọju lasiko naa, afaimọ ki wọn ma lu u pa, nitori oju araalu la lojiji, awọn eeyan ti ri ohun tawọn oloṣelu n ṣe, inu si bi wọn.

Ijọba mọ, awọn eeyan to si ti ri iru nnkan bayii naa mọ, pe ki i ṣe awọn ọdọ ti wọn bẹrẹ iwọde yii ni wọn pada bẹrẹ si i ji nnkan awọn oloṣelu ko, awọn araalu funra wọn, ati awọn janduku to ti wọ aarin wọn ni. Ki lo yẹ ko pa araalu ati janduku pọ, ko sohun to pa wọn pọ ju pe iya to n jẹ araalu n jẹ janduku naa, wọn si mọ pe awọn oloṣelu yii lo n fiya jẹ wọn, wọn si pinnu lati gbẹsan lara wọn. Nigba tawọn janduku ati araalu ba pade lati fiya jẹ awọn ti wọn n dari wọn bayii, ohun to maa n mu wa naa ni itajẹsilẹ nla, ija ẹlẹyamẹya ati iku ojiji fun awọn olowo ati ọlọrọ laarin ilu, nigba ti wọn ba ba nnkan wọn jẹ kọja afenusọ. Awọn ti wọn lọ sile awọn oloṣelu yii lati lọọ ko ẹru wọn, awọn eeyan wọn naa lo pọ ninu wọn: awọn ti wọn n sare tẹle mọto wọn ti wọn ba n lọ, awọn ọmọ ti wọn n lo lati fiya jẹ ẹlomi-in, ati awọn ti wọn jo tọju awọn ẹru yii, awọn naa lo gbẹyin yọ si wọn.

Bi ọrọ ti i di ogun ree, ti i di itajẹsile nla, bẹẹ araalu ki i sọ funra wọn tẹlẹ pe awọn fẹe ja, wọn aa kan bẹrẹ lẹẹkan naa ni, kinni naa yoo si maa ran kiri. Ko si ẹni ti mẹkunnu koriira laye yii bii olowo ati awọn ti wọn ri ṣe, awọn ti wọn ko ni anfaani lati sun mọ. Nigba ti iru anfaani yii ba waa ṣi silẹ lojiji, ti wọn le wọ ile olowo tabi da wọn lọna, wọn ki i fi oju aanu wo wọn rara, paapaa awọn aṣaaju ilu to ba ṣe wọn nika tẹlẹ, pipa ni wọn maa n pa wọn. Paripari ẹ ni pe orilẹ-ede ti ijọba ibẹ o ba ti daa, ti ko si iṣẹ lọwọ awọn ọdọ, ti inira pọ fawọn eeyan, ki i pẹ tawọn ero fi n pọ rẹpẹtẹ ni titi, ti ko si ni i sohun meji lọkan wọn ju ki wọn pa olowo, ki wọn si gba ohun yoowu ti wọn ba ri lọwọ wọn lọ. Awọn janduku bẹẹ ki i ṣee da duro mọ, nitori ko ni si olori ti ẹnikẹni le ba sọrọ, kaluku yoo maa ṣe tirẹ ni adugbo rẹ ni.

Bi ẹ ba wo awọn ti wọn n ko ẹru yii, ẹ oo ri i pe wọn ko mọ ara wọn ri, kaluku wa lati adugbo tabi ile ẹ ni, ibi ti wọn ti fẹẹ ko ẹru ni wọn ti pade. Bi ẹ ba si wo o daadaa, ẹ o ri i pe bi wọn ti n ṣe l’Ekoo, bẹẹ ni wọn n ṣe ni Pọta, ti wọn n ṣe ni Kalaba,  ti wọn n ṣe ni Jos, ti wọn n ṣe ni Abuja ati Kaduna, Yobe ati Adamawa. Bi ẹ ba si n wo wọn lọọọkan, ti ẹ ko ba sun mọ wọn ki ẹ gbọ ede ẹnu wọn, ẹ oo ro pe awọn ti wọn wa ni Kaduna naa ni wọn wa l’Ekoo, tabi pe awọn ti wọn wa ni Abuja naa ni wọn wa ni Enugu ni. Ohun to jẹ ki eleyii ri bẹẹ ni pe eeyan meji naa lo wa aye, mẹkunnu ati ọlọrọ naa ni, tabi talaka ati bọrọkinni, ẹni to ri jẹ ati ẹni ti ko ri jẹ. Ko si ilu ti eleyii ko si, nitori awọn meji ti wọn wa laye naa niyi. Bi ọrọ ba si ti da bayii, awọn talaka yoo duro ti ara wọn, awọn olowo naa yoo si wa ni ẹgbẹ keji, ohun to ṣe da bii pe awọn eeyan kan naa ni wọn n ṣe janduku yii kaakiri niyẹn.

Ohun to n ba mi lẹru ju lọ ni pe bi wahala ọdun 1964 ṣe bẹrẹ wẹrẹ naa ree, ti awọn oloṣelu ati ijọba igba naa n sọ pe ko si kinni kan, ko si wahala kan, ẹni to ba kọja aaye ẹ, awọn yoo gbe e ni, ti wọn ṣe bẹẹ titi ti wahala naa ko dawọ duro titi wọ 1965, ti ọrọ di ogun Wẹẹti-ẹ, to si pada di ogun abẹle nilẹ wa. Laarin ọdun kan si meji naa ni o, bo si ṣe bẹrẹ naa ree. Bo ba di lọsẹ to n bọ, ma a sọ itan naa ni ṣoki, ka le ri ohun mu ṣọgbọn. Ṣugbọn ẹ jẹ ka maa gbadura, dugbẹdugbẹ n mi lori awa Yoruba, ki Ọlọrun, Ọba to lọjọ oni yii, ma jẹ ko ja bọ le wa lori o.

One thought on “Bi irọ ba lọ logun ọdun…

Leave a Reply