Bi Kinsley ṣe fẹẹ wọn ṣọọṣi ni Festac lawọn agbebọn ji i gbe lọ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Awọn afurasi ajinigbe mẹta kan ti ji Ọgbẹni Kinsley Ogbuagu gbe lẹnu ọna ṣọọṣi to ti fẹẹ lọọ jọsin lọjọ Aiku, Sannde yii, ko si ti i sẹni to mọ ibi tọkunrin naa ha si di ba a ṣe n sọ yii.

Ba a ṣe gbọ, ni nnkan bii aago mẹfa aabọ owurọ ni ọkunrin naa de ileejọsin Catholic Church of the Visitation, to wa lagbegbe Festac, nijọba ibilẹ Amuwo-Ọdọfin, nipinlẹ Eko, wọn lo paaki ọkọ ayọkẹle to gbe wa sibi aaye igbọkọsi, o si pa Bibeli rẹ mọ ẹgbẹ, ṣugbọn bo ṣe ku diẹ ko de ẹnu ọna abawọle sileejọsin naa lawọn agbebọn mẹta kan yọ si i tibọntibọn, ti wọn si mu un lọ sinu ọkọ Lexus SUV ti wọn gbe sitosi, ni wọn ba wa ọkunrin naa lọ.

Ọkunrin ajafẹtọọ ọmọniyan kan, Harrison Gwamnishu, to jẹ ọrẹ Kingsley fi ikede nipa iṣẹlẹ naa sori atẹ ayelujara rẹ, o ni ọrẹ oun ti wọn ji gbe naa lo fi ọrọ ranṣẹ sori foonu oun pe wọn ti ji oun gbe, ati pe awọn mẹta ti wọn taari oun sẹyin ọkọ Lexus ti wọn gbe wa naa ki i ṣe ọlọpaa, gbogbo wọn ni wọn lo iboju dudu, oun o mọ inu igbo ti wọn wa oun lọ, o ni ki wọn ba oun sọrọ iṣẹlẹ yii fawọn famili oun ati awọn ọlọpaa lati gba oun silẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Adekunle Ajiṣebutu, sọ pe oun o ti i gbọ nipa ọrọ naa lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ṣugbọn o ni awọn ọlọpaa yoo ṣiṣẹ lori rẹ ti wọn ba gbọ hulẹhulẹ bọrọ naa ṣe jẹ gan-an.

Leave a Reply