Bi mi o ba yege ninu ibo abẹle, ma a pada sile mi-Tinubu

Ọrẹoluwa Adedeji
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, akọwe ijọba ilẹ wa tẹlẹ, Babachir Lawal ati ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin to n ṣoju awọn eeyan agbegbe Ikẹja, nipinlẹ Eko, Abiọdun Faleke, lo ṣaaju awọn eeyan ti wọn lọọ da fọọmu lati dupo aarẹ ti Aṣiwaju ẹgbẹ APC, Bọla Hammed Tinubu, gba pada l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Lasiko ti awọn eeyan naa atawọn alatilẹyin Tinubu mi-in ya bo ile ẹgbẹ APC niluu Abuja, nibi ti wọn ti da fọọmu naa pada ni Babachir ti ṣalaye fawọn oniroyin pe bo tilẹ jẹ pe Tinubu gba fọọmu ipo aarẹ naa pẹlu erongba lati jawe olubori ni, o ni eyi ko tumọ si pe bi ko ba jawe olubori, yoo da wahala eyikeyii silẹ, nitori ẹni to gbagbọ ninu ijọba awa-ara-wa ni.
O ni, ‘‘Pẹlu inu didun ni a fi waa da fọọmu aṣeyọri ti a gba lorukọ Aṣiwaju Tinubu pada, nipa igbesẹ ti a gbe yii, a ti ṣe ọkan ninu awọn alakalẹ ti ẹgbẹ wa gbe kalẹ fun ẹnikẹni to ba fẹẹ dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ APC, o si da wa loju pe didun lọsan-an yoo so fun wa lọjọ kọkanlelọgbọnjọ, oṣu Karun-un.
Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni Tinubu funra rẹ ti sọ ninu fidio kan to n ja rain kaakiri ori ẹrọ ayelujara pe bi oun ba kuna nibi ibo abẹle naa, oun yoo pada sile oun. Ṣugbọn oun gbagbọ ninu ṣiṣe ohun gbogbo ni ilana ijọba dẹmokiresi. O fi kun un pe gbogbo ohun to yẹ lati ṣe loun ti ṣe ni ipalẹmọ fun eto naa. Bẹẹ lo ni ki awọn ololufẹ oun fọkan balẹ.
Lati da fọọmu yii pada, ara alakalẹ ti ẹgbẹ APC fi silẹ fun awọn oludije ni pe awọn aṣoju kaakiri ilẹ wa to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC bii ọgbọn din ni irinwo (370), gbọdọ fọwọ si fọọmu wọn.
Ninu eyi ni Tinubu ti wẹ, to si ti yan kain-in-kan-in.

Leave a Reply