Bi mo ṣe n wo Tinubu lori tẹlifiṣan lẹnu ọjọ mẹta yii, niṣe laaanu ẹ n ṣe mi– Babachir Lawal

Faith Adebọla

Bi ọrọ ti akọwe agbatẹlẹ funjọba apapọ nileeṣẹ aarẹ, Ọgbẹni Babachir Lawal, sọ nipa oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati bi esi idibo ọhun yoo ṣe ri lọdun 2023 ba fi ja si ootọ, Bọla Tinubu ko ni i jawe olubori ninu idibo ọhun, koda ko le si nipo keji pẹlu, ọkunrin naa ni ipo kẹta lo maa wa, iyẹn bo ba mura daadaa ni. Bẹẹ ọkunrin yii ni ohun to da oun loju tadaa loun n sọ, o si yan-na-na idi abajọ bi ọrọ naa ṣe maa ri bẹẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti wọn ṣe fun un lori tẹlifiṣan Channels laṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla taa wa yii, lo ti la ọrọ ọhun mọlẹ, o ni ọrẹ timọtimọ loun ati Tinubu, ọpọ igba si lawọn maa n sọrọ titi dasiko yii, koda o loun ti sọ ootọ ọrọ yii fun un, oun ko si kuna lati sọ bọrọ ṣe jẹ, tori ọtọ laaye ọrẹ, ọtọ ni ka sọ okodoro otitọ funra ẹni.

Eyi ni diẹ ninu awọn alaye to ṣe:

“Ọmọ ẹgbẹ APC ṣi ni mi, mi o ti i kuro nibẹ, ṣugbọn a ti pinnu lati ṣatilẹyin fun Peter Obi, ti ẹgbẹ Labour.

“Ko too dasiko yii lawa ta a jẹ ẹlẹsin Kirisitẹni lapa Oke-Ọya ti ko ara wa jọ, awa alẹnulọrọ bii ogoji, latigba ta a ti ri i pe ojooro ati aiṣedajọ-ododo ni APC n ṣe fawọn Konigbagbọ, a si bẹrẹ si i ja fun ẹtọ ati iyansipo awọn Kirisitẹni ninu iṣẹjọba APC. Ti Bọla Tinubu yii kọ lakọọkọ.

“Tẹ o ba gbagbe, latigba ti APC ti fa oludije funpo aarẹ ati igbakeji ẹ ti wọn jẹ ẹlẹsin kan naa kalẹ ni mo ti sọ pe ko sọrọ nibẹ, ko tiẹ le ṣiṣẹ pẹẹ. Latigba naa lawa si ti n fori kori lati pinnu ewo ni ṣiṣe, o si gba wa lakooko ka too ṣepinnu, tori awọn kan ni ka ṣatilẹyin fun PDP, awọn kan ni Labour ni ka lọ. Lara awọn nnkan ta a ronu le lori ka too ṣepinnu ni pe ẹgbẹ ti ko ni i yan awa ẹlẹsin Kirisitẹni nipọsin, to si jẹ ẹgbẹ to rẹsẹ walẹ, to ṣee ṣe ko wọle.

“Ọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu yooku lo pe wa ba wa sọrọ, ṣugbọn APC ko wa, ko sẹnikan kan ninu wọn to tiẹ ṣe bii pe awọn ri wa, niṣe ni oludije funpo aarẹ wọn n ṣe bii p’oun ti wọle, bii pe mimi kan o le mi oun.

‘‘Ọrẹ mi ni Tinubu o, ko too di pe APC fa a kalẹ ni mo ti sọ fun un pe ko dupo aarẹ, tori mo ri i bii ẹni to le ṣe e, mi o ti i lalaa pe ma a di akọwe ijọba apapọ nigba yẹn. Ọrẹ ṣi ni wa di bi mo ṣe n sọ yii, ṣugbọn ọrọ to delẹ kọja ti ọrẹ.

‘‘Wọn ti foju awa Kirisitẹni l’Oke-Ọya gbolẹ, wọn ti yẹpẹrẹ ẹsin wa, wọn la o lẹnu nibẹ, a o kunju oṣuwọn, a o yẹ lẹni to gbọdọ wa nipo nla. Wọn ti ri ẹsin wa fin, wọn ti tẹmbẹlu wa, tori ẹ lo fi jẹ pe ẹnikẹni to ba tun maa bọ sipo aarẹ, pẹlu gbogbo agbara ati aṣẹ to rọ mọ ọn, ti yoo tun maa foju wa gbolẹ si i, a o le fara mọ ọn.

“Mo sọ fun un o, mo ni ọrẹ mi, to o ba lọọ ṣe aarẹ ati igbakeji ẹlẹsin kan naa, ọna wo lo fẹẹ gbe e gba ti wa a fi fẹyin Atiku (Abubakar) janlẹ, bawo lo ṣe fẹẹ ṣẹgun Kwankwaso (Rabiu Musa) l’Oke-Ọya? Fulani ẹlẹsin Musulumi ni Atiku, ọmọ alade ni l’Adamawa, ẹlẹẹkarun-un to maa jade dupo aarẹ ree, to si ti ni iriri kan tabi omi-in lori bi wọn ṣe n tayo yii, iwọ ṣẹṣẹ fẹẹ ṣe e lẹẹkinni ni, Buhari gan-an o wọle lori ẹlẹẹkinni, bo ṣe gbajumọ to. Awọn eeyan ti o ṣee gbẹkẹle ni Tinubu gbara le. Nibo ni Bọla ti fẹẹ ri ibo l’Oke-Ọya. Mo le fi da yin loju pe lawọn ipinlẹ to jẹ ti Hausa-Fulani, ko le ri ida mẹẹẹdọgbọn ninu ọgọrun-un ibo, ipinlẹ Borno nikan ni mi o le sọ, boya nitori ti igbakeji ẹ ṣa.

O maa padanu Adamawa, ibujokoo Atiku niyẹn. O maa padanu Gombe, tori wọn o nifẹẹ APC nibẹ, Taraba, Plateau, Benue, Nasarawa, o maa fidi rẹmi lawọn ibẹ yẹn, titi kan Kaduna paapaa, ibo lo ti waa fẹẹ ri ibo? “Boya o le ri ibo ni ilẹ Yoruba ṣa, tori bo ṣe n sọ pe awa lo kan, sibẹ ko le ri gbogbo ibo Yoruba gba, Atiku ṣi lagbara gidi nilẹ Yoruba paapaa.

Ki n ma tan yin, boya ti Kwankwaso ko ba ṣe daadaa to, Tinubu le ri ipo kẹta mu lasiko ibo, tori Kwankwaso gan-an maa ri ibo diẹ nilẹ Hausa, tori ọpọ awọn ti ko ri tikẹẹti ẹgbẹ APC lawọn ipinlẹ wọn, NNPP ni wọn kọri si. Ni ti Atiku, ẹ ma ba a du u, o maa ri ibo ni Ariwa ati Guusu gidi, tori alagbara ati ọlọgbọn oloṣelu ni, ẹgbẹ PDP rẹ si duro daadaa.

“Peter Obi maa ri ibo ida mẹẹẹdọgbọn lawọn ipinlẹ marun-un ilẹ Ibo, o si maa ri lawọn ipinlẹ mẹfa to wa ni Guusu inu lọhun-un, o maa ri ibo ni Aarin-Gbungbun Ariwa, ati ni Ila-Oorun Ariwa.

“Bi mo ṣe n wo Tinubu lori tẹlifiṣan lẹnu ọjọ mẹta yii, niṣe laaanu ẹ kan n ṣe mi, mo tiẹ n bi ara mi pe, abi Tinubu toju ẹ n dan tẹlẹ kọ lo ti waa da bayii?” Bẹẹ ni ọkunrin naa sọ o.

Leave a Reply