Bi Naijiria ba fi le pin, iya gidi ni yoo jẹ awọn ẹya keekeeke-Ọbasanjọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

L’Ọjọruu, ọjọ karun-un, oṣu karun-un, ọdun 2021, awọn akọṣẹmọṣẹ lati ilẹ TIV, ni Benue, wa Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ wa sile rẹ l’Abẹokuta, nitori ijinigbe ati ipaniyan to n ṣẹlẹ lapa ọdọ tiwọn naa.  Lọjọ naa ni Ọbasanjọ sọ pe omugọ eeyan lẹni to ba ro pe sisanwo itusilẹ fawọn ajinigbe ni ọna abayọ.

Ninu alaye to ṣe siwaju, Ẹbọra- Owu sọ pe oun ko nigbagbọ ninu sisanwo fun ajinigbe ki wọn le tu ẹni ti wọn ba mu sigbekun silẹ. O ni beeyan ba ti n sanwo fun ajinigbe ni wọn yoo maa tẹsiwaju lati maa ji awọn mi-in gbe si i, wọn yoo si maa fi owo ti wọn n gba naa ra nnkan ija ti wọn yoo tun fi doju kọ awọn to n sanwo fun wọn ni.

Lati yanju iṣoro ijinigbe yii, Oloye Ọbasanjọ sọ pe ijọba Naijiria ni lati wa ọna abayọ mi-in ni, eyi ti yoo nilo ọwọ rirọ ati lile nibi to ba ti yẹ.

O ni ẹni ti ko ni i sanwo fun ajinigbe, to si fẹẹ gba awọn eeyan rẹ kuro lọwọ ajinigbe gbọdọ ni ọna to lagbara ti yoo fi yanju rẹ ni o.

Ọbasanjọ sọ pe kaka kijọba maa sanwo fajinigbe bayii, ki wọn wa ọna mi-in ti wọn yoo fi maa yanju ẹ ni.

‘’Ijọba ko ṣẹṣẹ maa sanwo fawọn ajinigbe, ki i ṣe ijọba to wa lode yii nikan, koda laye ijọba Jonathan, wọn sanwo fawọn ajinigbe. Bẹẹ, wọn yoo maa purọ pe awọn ko sanwo kankan’’ Bẹẹ l’Ọbasanjọ wi.

Lori awọn to n fẹ ki Naijiria pin, aarẹ Naijiria tẹlẹ naa sọ pe wọn ko ro ti awọn ẹya keekeeke mọ ọn ni. O ṣalaye pe bi iran Yoruba, Hausa ati Ibo ba le da duro, awọn ẹya mi-in ti wọn wa lorilẹ-ede yii nkọ.

Baba sọ pe bi gbogbo wa ṣe wa pọ yii lo n ṣiji bo awọn ẹya mi-in ti ko le da duro, bi Naijiria ba si fi pin pẹnrẹn, iya gidi ni yoo jẹ awọn ẹya to ku yẹn.

O fi kun un pe olori Naijiria to ba n ro ti ẹya rẹ nikan ko le rọna lọ, nitori apapọ ilu ṣagba ẹya ẹyọ kan ṣoṣo.

Bakan naa l’Ọbasanjọ sọrọ lori 2023. O ni awọn olori Naijiria gbọdọ ri i pe nnkan yipada lọdun 2023, ai jẹẹ bẹẹ, Naijiria le lọ si okun igbagbe, ki ipinya de.

Olori awọn TIV to waa ba Ọbasanjọ, Ọjọgbọn Zacharya Anger Gundu, ṣalaye pe ẹjẹ n ṣan nipinlẹ Benue, latari iku awọn tawọn Fulani agbebọn pa.

Ọkunrin yii sọ pe oju oorun lawọn agbebọn ti waa n pa awọn eeyan ni Benue, lori ilẹ baba wọn.

Ọjọgbọn Gundu ni k’Ọbasanjọ atawọn eeyan to jẹ alẹnulọrọ ni Naijiria dide, ki wọn kọ orile-ede yii lọna abayọ tootọ.

O ni o yẹ kijọba ṣeto iranwọ fawọn eeyan to padanu eeyan wọn ninu ikọlu, atawọn ti wọn ti gba ile gba oko wọn, ki wọn si paṣẹ fawọn darandaran pe ki wọn yee da ọran, ki wọn yee fi kiko ẹran jẹ kiri ba aye alaye jẹ.

Leave a Reply