Bi nnkan ṣe n lọ yii: Naijiria le fọ si wẹwẹ ni 2023

*Awọn Hausa-Fulani yii ko fẹẹ gbejọba silẹ ni o

Ademola Adejare

Naijiria jagun abẹle. Ogun to buru gbaa ni o. Laarin ọdun 1967 si ọdun 1970. Ọdun mẹta gbako. Akọsilẹ fi han pe bii miliọnu meji eeyan lo ba ogun naa lọ. Laarin awọn ṣọja ni ija naa ti bẹrẹ, ṣugbọn ki i ṣe awọn gan-an ni wọn da ija naa silẹ. Awọn oloṣelu ni. Ija, irẹjẹ ati iwa ibajẹ nla lo gbilẹ laarin awọn oloṣelu, nigba ti wọn si bara wọn ja de aaye ibi kan, awọn ṣọja fibinu gbajọba lọwọ wọn. Ṣugbọn awọn ṣọja ti wọn gbajọba naa, irẹjẹ ati ikunsinu to ti wa laarin awọn naa ko ṣee bo mọlẹ, o ti gbilẹ gidi gan-an. Ko si si ohun to fa a ju pe awọn ti wọn n ṣe olori ijọba igba naa ti wọn jẹ awọn ẹya Hausa-Fulani lo gbogbo ọna ti wọn mọ lati gbe awọn ẹya wọn leri gbogbo eya to ku, ati lati maa fi wọn ṣe olori ijọba Naijiria, bo tilẹ jẹ pe nigba naa, iriri ati ọgbọn iwe wọn ko to bẹẹ rara. Nibi ti wahala ti bẹrẹ niyẹn.

Awọn Hausa-Fulani yii ti Sardauna Ahmadu Bello jẹ olori wọn ko fi kinni kan silẹ fun awọn ẹya to ku, afi awọn ti wọn ba foribalẹ si abẹ wọn nikan. Nidii eyi, wọn da ija silẹ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu to ku, ẹnikẹni to ba si ti fara mọ iwa ibajẹ ti wọn n hu yii ni wọn yoo ti lẹyin, nigba to si jẹ awọn ni wọn n ṣakoso awọn ṣọja ati ọlọpaa, gbogbo ohun ti wọn ba fẹ ni i ṣee ṣe fun wọn. Wọn sọ awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu ti wọn jẹ alatako wọn bii Ọbafẹmi Awolọwọ sẹwọn, wọn si lu ẹgbẹ oṣelu tirẹ fọ patapta. Wọn fi oye ti ko lagbara kan tan Nnamdi Azikiwe, wọn si ri i pe wọn da ẹgbẹ oṣelu rẹ naa ru, debii pe awọn nikan lo ku, ẹgbẹ ilẹ Hausa, NPC, nikan lo ku to jẹ ẹgbẹ oṣelu to fẹsẹ mulẹ, oun naa si ni awọn to ku n ba ṣe. Bo si tilẹ jẹ pe ibinu awọn eeyan ru soke si wọn, ti wọn ko fẹ ohun ti wọn n ṣe yii, ko sohun ti wọn le ṣe.

Nigba yii ni awọn ṣọja kan ati ọkunrin Ibo ti wọn n pe ni Kaduna Nzeogwu dide laarin awọn ẹlẹgbẹ rẹ, o si ko awọn mi-in jọ, ni wọn ba fibọn gbajọba, wọn si pa awọn Sardauna, Balewa, Akintọla ati awọn mi-in ti wọn jọ wa nidii ibajẹ to ti ba awọn oloṣelu lati ọjọ yii wa. Ṣugbọn ọrọ naa ko tẹ awọn ṣọja ilẹ Hausa to ku lọrun, nigba to jẹ awọn ọga ṣọja to wa lati ọdọ wọn wa ninu awọn to ku. Inu si tubọ bi wọn si i nigba ti wọn ri i pe ọmọ Ibo lo ṣaaju awọn ti wọn yinbọn pa wọn. Bẹẹ, ni tododo, inu n bi awọn ṣọja ọmọ Ibo yii ni kọrọ tẹlẹ, ati awọn Yoruba kọọkan. Ohun to si fa a naa ni pe ki Naijiria too gba ominira ni 1960, awọn Ibo lo ni ọga ninu ṣọja ju ẹya mi-in ni Naijria lọ. Laye oyinbo lọrọ naa ti ri bẹẹ, awọn Yoruba lo ku to tẹle wọn. Nibi ti awọn Ibo ti ni bii ọga marun-un, ti Yoruba ni ọga mẹta, meji pere ni tawọn Hausa.

Eyi ni pe ko too di pe awọn oyinbo gbejọba yii silẹ, awọn Ibo lo n dari ọmọ ogun orilẹ-ede yii, nitori awọn ni wọn ni awọn ọga ṣọja to pọ ju lọ. Ṣugbọn ni gbara ti Naijiria gba ominira, ti ijọba si bọ sọwọ awọn Hausa-Fulnai, kia ni wọn yi ohun gbogbo pada, wọn si din iwe to yẹ ki ẹni to ba fẹẹ wọ ṣọja ka ku, bẹẹ ni wọn ṣeto pe bi wọn ba ti pọ to ni agbegbe kan ni wọn yoo fi maa ko awọn eeyan siṣẹ ṣọja, ti wọn yoo si ma sọ wọn dọga, ati awọn eto mi-in bẹẹ, nigba ti yoo si fi di ọdun 1965, awọn ọga ṣọja lati ilẹ Hausa ti gbe awọn ti Ibo ati Yoruba min. Paripari rẹ si ni pe ọpọ ninu awọn ti awọn ọmọ Ibo wọnyi pada waa kọ niṣẹ tun di ọga wọn. Iru rẹ ni Muritala Muhammed ti Emeka Ojukwu kọ niṣẹ ologun, atawọn mi-in bẹẹ. Eyi jẹ ki ibinu ati ija orogun wa laarin awọn ọga ṣọja lati ilẹ Ibo ati awọn to gba ipo wọn lati ilẹ Hausa.

Nidii eyi, nigba ti wọn fibọn gbajọba, to si jẹ awọn Ibo lo pọ ninu awọn ti wọn ṣe kinni naa, ibinu awọn ọga ṣọja lati ilẹ Hausa ru soke, wọn si n wa gbogbo ọna lati gbẹsan. Wahala naa tilẹ waa pọ nigba ti awọn Nzeogwu to ditẹ gbajọba naa ko le ṣe e, ti wọn ni ọga agba ju lọ ninu iṣẹ ologun lo gbọdọ ṣe olori ijọba. Ibo ni iyẹn naa, Aguiyi Ironsi. Oun ni ko lo ju oṣu mẹfa lọ ti wọn fi yinbọn pa a, awọn Hausa lo ṣe iyẹn. Nigba ti wọn pa a tan ni wahala bẹrẹ, Ojukwu to ti di gomina ilẹ Ibo ni nigba ti wọn ti le pa ẹni to jẹ olori ijọba, ọga ṣọja to ba tun pọwọ le e ni ko gbajọba. Bo ba jẹ wọn fẹẹ mu eyi ṣẹ, ọmọ Yoruba kan to jẹ igbakeji Ironsi, Babafẹmi Ogundipẹ, ni iba ṣe olori ijọba Naijiria. Ṣugbọn awọn ṣọja Hausa yii lawọn ko ni i gba ki Ogundipẹ, tabi ki ẹya mi-in ti ki baa ṣe Hausa ṣe olori awọn. Eyi ni wọn fi mu Yakubu Gowon, ti oun si di olori ijọba.

Eyi naa lo bi Ojukwu ninu pe ẹni to kere ninu iṣẹ ologun ko le waa ṣe olori awọn ti awọn jẹ ọga rẹ, pe ko gbejọba fẹni to ga ju u lọ. Awọn Gowon ko gba. Ati pe nigba naa, awọn Hausa ti bẹrẹ si i wa awọn ẹya Ibo to wa niluu wọn kaakiri, lati Kaduna de Sokoto, lati Kano de Zaria, ati de Katsina, wọn kan pa wọn lọọ ṣaa ni. Nibi yii ni ogun abẹle ti bẹrẹ, nitori wọn o pari ija naa, ko ṣee pari, ọrọ naa lo si di ogun nla to gbẹmin awọn eeyan to sun mọ ẹgbaagbeje (2.8m). Ni ibẹrẹ, gbogbo aye lo n da awọn Ibo lẹbi, wọn si n da Ojukwu to ṣaaju awọn ọmọ ogun Biafra yii lẹbi, wọn ni oun lo da ogun silẹ. Ṣugbọn nigba ti ogun pari, ti iwadii ijinlẹ si bẹrẹ lori ohun to fa ogun yii loootọ, o han pe awọn oloṣelu lati ilẹ Hausa lo da eyi to pọ ju ninu ọrọ naa silẹ, ati pe awọn ṣọja lati ọdọ tiwọn ti wọn fi tipa tipa gbe le awọn ọga wọn lori pẹlu irẹjẹ lo jẹ kọrọ naa di tawọn ologun. Ohun to wa n ba awọn eeyan lẹru naa niyi o.

Ohun to fa idi ibẹru yii ni pe iru awọn irẹjẹ to ṣẹlẹ lọdun naa lọhun-un, awọn irẹjẹ naa ti pada de bayii, awọn irẹjẹ yii si ju ti asiko awọn oloṣelu ilẹ Hausa ọjọsi lọ. Awọn Kristẹni ti n pariwo gidi bayii, nitori o fẹrẹ jẹ gbogbo ibi ti wọn wa ni Kaduna, ati ni agbegbe awọn Tiv, ni Benue, Plateau, gbogbo ibẹ lawọn Fulani onimaalu ti n pa wọn kaakiri. Bakan naa ni wọn si ti wọ ilẹ Yoruba, ti wọn n pa awọn eeyan. Ohun to waa buru, to si n mu ibẹru wa ni pe ijọba to wa lode yii ko ṣi wọn lọwọ ohun ti wọn n se yii, bi aburu yii si ti n pọ to, bẹẹ nijọba n yi oju si ẹgbẹ kan si i. Eyi ti waa jẹ ki awọn eeyan ti wọn ki i ṣe Fulani bẹrẹ si i runra ni Naijiria, ti wọn si n fọhun jade pe o da bii pe ijọba yii fẹẹ gba ilẹ to jẹ ti awọn ẹya mi-in fun awọn Fulani alarinkiri yii ni, ki wọn le ribi maa gbe, ki wọn si sọ ilẹ onilẹ di tiwọn.

Yato si eyi, ọpọlọpọ ohun-ini, awọn ohun alumọọni ati ajogunba to jẹ ti awọn ẹya mi-in, paapaa ni awọn ipinlẹ wọn ni ijọba yii n fi ofin ati agidi gba sọdọ tiwọn, nigba ti wọn si mọ pe nigbẹyin, awọn Fulani ni wọn yoo fun lanfaani lati lo kinni naa. Ọna oju omi gbogbo ni orilẹ-ede yii, ijọba apapọ ni awọn yoo gba a ki wọn le gbe e si abẹ awọn eeyan wọn lati maa dari, ile ifowopamọ ilẹ wa, ileeṣẹ elepo ilẹ wa, ileeṣẹ ologun gbogbo nilẹ wa, gbogbo awọn nnkan wọnyi ni ijọba yii ti fi ọgbọn gba, ti wọn si gbe wọn si abẹ awọn eeyan lati ilẹ Hausa tabi awọn ẹya Fulani wọnyi. Ni ojoojumọ ni wọn n kowo buruku ti ko ṣee fẹnu royin jẹ. Ṣugbọn bo ba ti jẹ awọn ẹya tiwọn ni wọn ko owo yii min, koda ki ariwo ọrọ naa jade, wọn yoo mọ bi wọn yoo ti pa ina rẹ mọlẹ ni. Ni ojoojumọ ni irẹjẹ naa n pọ si i loju awọn eeyan, ti wọn ko si rohun ti wọn le ṣe.

Ohun kan lawọn araalu fẹẹ ṣe, iyẹn naa ni pe wọn ti mọ pe nigba ti yoo ba fi di ọdun mẹta si asiko yii, iyẹn lọdun 2023, ijọba yoo kuro lọwọ awọn eeyan ilẹ Hausa, yoo si bọ si ọwọ Ibo tabi Yoruba, awọn yoo si le fi asiko naa tun awọn nnkan ti awọn eeyan yii n bajẹ ṣe. Gbogbo ohun to dorikodo, ati irẹjẹ to fẹẹ da Naijiria ru bayii, gbogbo rẹ lawọn ti wọn n woye ọrọ ni yoo yipada bi ijọba ba ti kuro lọwọ awọn eeyan yii. Ṣe gẹgẹ bii eto to wa nilẹ, bi awọn ara Guusu (Ilẹ Yoruba ati Ibo tabi Delta) ba ṣejọba tan, awọn ara Ariwa (Ilẹ Hausa) naa yoo ṣe. Gẹgẹ bi eto ti lọ yii, awọn ara ilẹ Yoruba ti ṣe, laye ijọba Ọbasanjọ, Yar’Adua naa si ti ṣe gẹgẹ bii eeyan lati Ariwa nilẹ Hausa. Jonathan naa ṣe lati ilẹ Delta, ni Guusu, Buhari naa si n ṣe ijọba rẹ lọ bayii lati apa Ariwa. Bi Buhari ba kuro ni 2023, ẹtọ ni ki eeyan kan lati Guusu tun bọ sibẹ gẹgẹ bii olori ijọba. Eleyii lawọn aṣaaju Hausa wọnyi ko fẹ ko ṣẹlẹ mọ, ibi ti biliisi yoo si ti de niyẹn.

Nigba tọrọ naa kọkọ bẹrẹ, ti awọn eeyan lati ilẹ Hausa bẹrẹ si gbegi dina, ti wọn si n tu awọn aṣiri kan jade nipa Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ohun tawọn eeyan kọkọ n ro ni pe Tinubu ni wọn ko fẹ, wọn yoo mu eeyan mi-in ti wọn ba fẹ lati ilẹ Yoruba, bo si jẹ apa ilẹ Ibo ni. Ṣugbọn ni bayii, ko jọ pe ohun to ṣẹlẹ ree, o jọ pe gbogbo ọna lawọn eeyan naa n wa lati fi ma gbe ijọba silẹ, ko jẹ ọdọ Hausa mi-in ni wọn yoo tun gbe kalẹ pe ko maa ṣejọba Naijria lọ ni. Iroyin ko yee pariwo orukọ Nasir El-Rufai to n ṣe gomina ipinlẹ Kaduna bayii, awọn eeyan si n fẹsun kan an pe nitori o fẹẹ di Aarẹ, ti ko si fẹ ki awọn Fulani kọyin si oun lati asiko yii lo ṣe yiju si ẹgbẹ kan bi awọn Fulani onimaaluu ṣe n fi ojoojumọ paayan ni ipinlẹ rẹ, ti ko si ri ohun kan bayii ṣe si i ju ko tun maa bu wọn lọ, pe awọn Kristẹni ni wọn kọkọ n waja wọn lọ.

Aipẹ yii ni olori ile-igbimọ aṣofin kekere tẹlẹ jade kuro ninu PDP, to ti sa lọ tẹlẹ, to ni oun pada wa sinu APC. Ohun ti awọn eeyan kọkọ gbe jade ni pe wọn fẹ ko waa ṣe igbakeji fun Tinubu lasiko ibo to n bọ ni 2023 yii ni, ṣugbọn ALAROYE ti fi ẹsẹ rẹ mulẹ pe ko si ohun to jọ bẹẹ, oun ba tirẹ wa ni, awọn kan si ti n ṣeto bi wọn yoo ti ṣe fi i ṣaaju pẹlu atilẹyin Buhari ati awọn eeyan rẹ, ti wọn yoo ni ko du ipo Aarẹ. Ko si ẹni to ti kọkọ ro pe eleyii yoo ṣee ṣe ju igba ti ẹnikan to sun mọ Buhari pẹkipẹki, ẹni ti ẹnu ti kun titi pe oun gan-an lo n dari aburo rẹ yii, nitori ẹgbọn Buhari lo n ṣe, to jade, to ni ki ijọba pa eto ki olori maa wa lati awọn ẹya ni jẹ-ki-n-jẹ rẹ, pe ẹni yoowu to ba kun oju oṣuwọn, to si ti ni iriri to to ni ki wọn maa fi ṣe Aarẹ. Ọkunrin naa mọ pe awọn ara Guusu lo gbọdọ fa Aarẹ kalẹ lasiko yii, idi to si fi n sọ bẹẹ ni pe bi eleyii ba fi le wọle, wọn yoo ni awọn ọmọ ilẹ Hausa le jade niyẹn igba to ba wu wọn lati du aarẹ.

Bi awọn Hausa ba waa debẹ, ọrọ naa yoo le diẹ, nitori oju kan ni wọn yoo dibo wọn si, wọn yoo si lo ariwo pe awọn lawọn pọ ju la ti fi ṣe ojooro ibo naa si ọdọ wọn. Bi wọn ba ti fi ojoro ṣeto ibo naa si ọdọ wọn ti wọn ni ọmọ Hausa mi-in lo wọle, wọn yoo bẹrẹ si i fi ọlọpaa ati ṣọja halẹ mọ gbogbo ẹni to ba fẹẹ di wọn lọwọ, wọn yoo si ti ọpọlọpọ mọle ki ijọba wọn tuntun naa le ṣee ṣe. Awọn kan ti wa n leri silẹ de wọn bayii pe ni ọọkan ibi ti Naijiria yoo ti fọ si wẹwẹ ree, bi iru rẹ ba fi le ṣẹlẹ lẹẹkan si i. Ohun ti yoo mu ifọsiwẹwẹ yii ṣẹlẹ ni pe ọrọ ijọba awọn Hausa-Fulani, ati ọpọlọpọ iwa irẹjẹ ati aburu wọn, nibi ti awọn mi-in ti n sọ ọ kan awọn ẹya to ku loju pe awọn lawọn ni Naijiria, awọn to ku n ba awọn ṣe e lasan ni, ti de gongo fawọn eeyan, ajaga ti wọn di ru ilu lori yii si ti di ohun ti kaluku fẹẹ yọ kuro lọrun.

Ni ọsẹ to kọja yii, ẹgbẹ apapọ awọn ọmọ Yoruba ti wọn n pe ni Yoruba World Congress ti mu orukọ Yoruba wọ inu ẹgbẹ agbaye kan ti wọn n pe ni UNPO, ẹgbẹ awọn ẹya ti wọn ko ni alafẹyinti, tabi awọn ẹya ti wọn n rẹ jẹ laarin orilẹ-ede wọn. Olori ẹgbẹ Yoruba World Congress yii, Ọjọgbọn Banji Akintoye, sọ pe ohun to mu Yoruba lọ sinu ẹgbẹ yii ko ju irẹjẹ ati iwa ika ti awọn Hausa-Fulani n hu si wọn lọ. Ọjọgbọn naa ni lati bii ogoji ọdun bayii lawọn ẹya yii ti fa Yoruba sẹyin, ti wọn si di wọn lọwọ, ti wọn ko jẹ ki wọn dagba soke mọ, ti wọn ko gbogbo ohun-ini Yoruba sabẹ wọn, ti wọn si n lo o bi wọn ti fẹ, to si jẹ bi wọn ba lo o titi naa, wọn yoo pada ba a jẹ ni. Ọjọgbọn naa ni awọn Hausa-Fulani wọnyi ko ni eto fun Yoruba, ohun ti wọn n tori ẹ ṣe Naijiria ni tiwọn ko ju ki wọn fawọn mi-in ṣe ẹru lọ, nigba ti Yoruba ko si ni i ṣe ẹru ẹni kan, o di dandan ki wọn jade wọọrọ kuro ni Naijiria, lai ni i mu ija dani rara.

Lọjọ ti awọn lọ yii naa ni awọn Biafra lọ sibi ipade UNPO yii, ọjọ yii kan naa ni wọn si gba awọn naa wọle sinu ẹgbẹ yii, ẹjọ kan naa ti awọn paa ro fun wọn nibẹ ni pe Naijiria n rẹ awọn jẹ, awọn ko ṣe mọ, ifiyajẹni naa pọ, bi wọn ko ba si jẹ ki awọn jade kuro ni Naijiria wọọrọ, ọrọ naa le dogun lawọn ṣe wa sinu ẹgbẹ agbaye yii. Ṣe ko too di asiko yii ni ẹgbẹ awọn ọdọ ilẹ Ibo naa ti wa, ti wọn ti n sọ pe awọn ki i ṣe ọmọ Naijiria, Biafra lawọn, iyẹn ẹgbẹ MASSOB ti Nnamdi Kanu jẹ olori wọn. Awọn yii ti ja, ti wọn si ti fi gba kan koju ijọba Buhari yii, wọn ti da aṣọ ṣọja wọn pada si aṣọ ọlọpaa tiwọn, wọn si ṣe owo Biafra ti wọn ni awọn yoo maa na. Ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba naa ni wọn wa lẹyin odi, ti wọn ni afi ki Yoruba kuro ni Naijiria, bẹẹ ni awọn ọmọ Naija-Dẹlta ati awọn aṣaaju wọn pọ ti wọn ni awọn ko ṣe Naijiria yii mọ.

Ohun tawọn agba, ati awọn ọjọgbọn aye waa n tẹ wọn lẹsẹ si, ohun ti wọn n tori rẹ da wọn duro naa ni ibo ọdun 2023, pe ki wọn ni suuru, ẹya mi-in yoo gbajọba Naijiria nigba naa, ohun gbogbo yoo si yipada. Ṣugbọn kinni naa ni ko fẹẹ ṣee ṣe yii, bi ko ba si ti ṣee ṣe, Naijiria yii le fọ si wẹwẹ ko too digba naa, tabi nigba naa gan-an. Ki eku ile gbọ, ko sọ fun toko o.

2 thoughts on “Bi nnkan ṣe n lọ yii: Naijiria le fọ si wẹwẹ ni 2023

  1. E jowo, itan ti e o mo, è mà so nipa re mo. Iro lo po ninun oun ti e so yi. Se nitori ki Yoruba da wa, ni gbogbo itan iro ti e ko yi? E beru ELEDUA!!!

Leave a Reply