Bi ole ba fi le fọ banki kankan lasiko yii n’Ijẹbu-Ode, awọn oṣiṣẹ ibẹ ni afurasi akọkọ- Kọmandi ọlọpaa Ogun

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Pẹlu bawọn banki gbogbo n’Ijẹbu-Ode ṣe kọ ti wọn ko ṣilẹkun, ti wọn ni awọn gba lẹta latọdọ awọn adigunjale pe wọn n bọ waa fọ banki, Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti binu sawọn banki yii. Wọn ni bi idigunjale ba fi le waye pẹnrẹn ni banki eyikeyii n’Ijẹbu-Ode ati agbegbe ẹ lasiko yii, awọn oṣiṣẹ banki naa lawọn yoo mu gẹgẹ bii afurasi akọkọ.

Ọsan ọjọ Sannde ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ni Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi atẹjade to ṣalaye nipa igbesẹ awọn banki yii sita.

Oyeyẹmi sọ pe aiṣilẹkun awọn banki yii ko nitumọ meji ju pe eletekete ni wọn lọ.

O ni nibi ti ko ti si idi fun ẹnikẹni lati ko aya soke ni awọn banki yii ti n da ijaya silẹ, eyi si fi han pe wọn ko kunju oṣuwọn, wọn ko si mọ iṣẹ wọn.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe awọn ti ba awọn banki yii sọrọ lori ti idigunjale ti wọn wi naa, awọn beere lẹta ti wọn ni ole kọ si wọn pẹlu, wọn ko ri lẹta kankan mu jade. Eyi to fi han pe awọn onileeṣẹ ifowopamọ naa kun fun ete ati abosi,wọn si fẹran ki wọn maa da wahala silẹ ni.

Yatọ si ileeṣẹ ọlọpaa, Alukoro sọ pe awọn ẹka aabo to ku nipinlẹ Ogun naa ko kawọ gbera lori eto aabo, gbogbo awọn lawọn jọ fi ọkan awọn banki adarugudu silẹ yii balẹ pe ko si ewu, ṣugbọn wọn ko gbọ, wọn taku, wọn ko ṣilẹkun, wọn ko ṣiṣẹ wọn .

Bi idigunjale ba fi waa ṣẹlẹ ni banki kan n’Ijẹbu-Ode ati agbegbe ẹ lasiko yii, awọn ọlọpaa Ogun sọ pe awọn banki ti wọn n tilẹkun pa lai nidii yii lawọn yoo kọkọ mu gẹgẹ bii afurasi, nitori awọn ni wọn pe ṣoṣo ti wọn ri ṣoṣo.

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun naa si ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa ṣiṣẹ iwadii gidi lori lẹta ole tawọn banki sọ pe awọn gba naa, ki gbogbo ohun to ṣokunkun le han lode kedere.

Ṣe lati ọjọ Mọnde to kọja yii ni awọn banki ko ti ṣilẹkun n’Ijẹbu-Ode ati agbegbe ẹ, nigba to si ya gan-an, awọn ọlọja keekeeke tawọn naa ni sọọbu lagbegbe bẹrẹ si i yan ṣọọbu wọn lodi, wọn ko ṣilẹkun nitori ẹru n ba wọn pe idigunjale to ba kan banki yoo kan awọn naa tawọn mule ti ileefowopamọ, ni ohun gbogbo ba dakẹ jẹ labala kara-kata.

Ṣugbọn pẹlu ikilọ awọn ọlọpaa lẹẹkeji yii, to si tun jẹ ọsẹ tuntun ree, o ṣee ṣe kawọn olokoowo kereje ṣilẹkun tiwọn.

Leave a Reply