Jide Alabi
Ileeṣẹ ologun Naijiria ti sọ pe igbesẹ ti gomina ipinlẹ Eko gbe lori bo ṣe ranṣẹ pe awọn ologun lati waa koju wahala tawọn janduku kan da silẹ lasiko rogbodiyan SARS tọna daradara.
Ahmed Ibrahim Taiwo, ọkan lara awọn ọgagun ninu iṣẹ ologun, lo sọrọ yii niwaju igbimọ to n gbọ ẹjọ nipa rogbodiyan to ṣẹlẹ ni too-geeti Lẹkki, ati gbogbo ọrọ tọ jẹ mọ wahala tawọn ẹṣọ agbofinro SARS ko ba araalu, eyi to pada da wahala nla silẹ.
Ọkunrin ologun yii sọ pe nigba ti eto iṣakoso ipinlẹ Eko fẹẹ di rudurudu nipasẹ rogbodiyan to n ṣẹlẹ kaakiri ni Gomina Sanwo-Olu ṣe sare ke si awọn, ati pe igbesẹ yẹn gan-an lo dara ju niru asiko bẹẹ yẹn pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe ri nigba naa.
Tẹ o ba gbagbe, ni kete ti ọrọ bẹyin yọ lori bi awọn ṣọja ṣe kọ lu awọn ọdọ to lọọ ṣewọde ta ko SARS ni Lẹkki ni Gomina Babajide Sanwo-Olu ti sare bọ sita, ohun to si sọ ni pe oun ko ranṣẹ pe ṣọja kankan, awọn ti wọn lagbara ju oun lọ gan-an lo ṣe e.
Bi ọrọ yẹn ṣe di ariyanjiyan nla niyẹn, nigba to ya lawọn ṣọja naa bọ sita, ti wọn si sọ pe awọn ki i da sọrọ ti ko ba kan awọn, Sanwo-Olu gan-an lo ni ki awọn maa sare lọ si Lẹkki, ki ọrọ too di bo ṣe da bayii.
Oga awọn ologun naa ni gbogbo ẹri ti awọn ko wa ati aworan to han nibi iṣẹlẹ naa ti fi han pe loootọ, Sanwo-Olu lo ranṣẹ pe awọn.