Bi wọn ba ni Wike wọle sibi kan lasiko idibo aarẹ Naijiria, yara rẹ lo ko si-Ganduje

Monisọla Saka
Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje, ti ba ojugba rẹ nipinlẹ Rivers, iyẹn Nyesom Wike, sọ ootọ ọrọ lori erongba rẹ lati dupo aarẹ lọdun 2023.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti Ganduje gbalejo Wike nile ijọba, nipinlẹ Kano, lo sọ fun un pe wọn yoo fẹyin rẹ janlẹ ninu ibo aarẹ ọdun 2023, ati pe yoo ru poo ni.
Gomina ipinlẹ Kano to sọrọ naa tẹrin-tẹrin ni oun yin Wike lawo pe o tiẹ jade lai dupo arẹ ọdun 2023.
O ni, “O waa ri awọn eeyan rẹ lọkunrin ati lobinrin, abi? O daa bẹẹ. O fẹẹ jade gẹgẹ bii aarẹ Naijiria. Mo si mọ pe nigbẹyin gbẹyin, o o ni i wọle, amọ yoo daa pe o tilẹ gbiyanju.
Ninu ọrọ rẹ, Wike ni inu oun dun pe gomina ipinlẹ Kano ko si ninu ere ije ipo aarẹ ọhun, o waa rọ ọ pe ko dakun, ko ṣatilẹyin foun ninu ibo ọdun to n bọ. O ni ti Ganduje ba jade dupo aarẹ, gbogbo awọn lwọn maa sare yọwọ yọsẹ pe awọn ko ṣe mọ, ṣugbọn Ọlọrun ṣeun ti ko jade. Ọkunrin yii ni o da oun loju pe Ganduje yoo kun oun lọwọ lati de ebute ogo”.
Ṣaaju akoko yii ni Wike ti lọọ ri awọn jankan jankan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lori ibo abẹle Aarẹ ẹgbẹ wọn.
Nigba ti Wike n ba awọn eeyan ọhun sọrọ, o ni akoko ti to lati mu ayipada ba aṣiṣe to gbe agbara ijọba le awọn ẹgbẹ oṣelu APC lọwọ.
O waa tẹsiwaju pe oun n fara oun kalẹ gẹgẹ bii oludije to kunju oṣuwọn ju lati gbogo PDP ga pada.
Gomina Wike tẹnu mọ ọn pe eeyan bii oun lo le fopin si ọrọ eto aabo to dẹnu kọlẹ ati iṣẹ oun oṣi to n ba awọn eeyan wọya ija kaakiri orilẹ-ede.
O rawọ ẹbẹ si Ganduje ati awọn eeyan ilẹ Naijiria lati tuyaaya jade ki wọn fi ibo gbe e depo aarẹ, ki erongba rẹ lati fopin si kudiẹ kudiẹ ti ijọba APC ko wọ ilẹ wa le wa si imuṣẹ.

Leave a Reply