Bi wọn ba pa Igboho, itajẹsilẹ ati ogun ni wọn n kọwe si yẹn-Gani Adams

Faith Adebọla

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Ọtunba Gani Adams, ti koro oju si bi awọn kan ṣe kọ lu ile ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Igboho. O ni ọna lati jẹ ki ọkunrin naa dakẹ, ko ma le sọrọ mọ nipa aidaa to n lọ nilẹ Yoruba lo mu ki wọn maa gbe igbeṣẹ naa. Bẹẹ lo rọ ijọba lati wadii awọn to ṣiṣẹ buruku ọhun.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Aarẹ lori eto iroyin, Kẹhinde Aderẹmi, fi sita lo ti ni bi wọn ṣe kọ lu ile Igboho jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ gidigidi, ohun ti eyi si fi han ni pe ijọba ko naani ẹmi awọn ọmọ orileede yii, bẹẹ ni ko si ẹmi ẹnikankan to de ni Naijiria yii.

Aarẹ ni awọn ti n jijagbara fun ilẹ Yoruba ni ijọba n doju ija ko, bi wọn si ṣe kọ lu ile Sunday Igboho lẹẹmeji laarin oṣu mẹfa fi han pe ọrọ naa ki i ṣe oju lasan rara.

O fi kun un pe nitori ijagbara ọmọ Yoruba ti Igboho n ja ni wọn fi doju ija kọ ọ, o waa ni afi ki wọn kilọ fun awọn to wa lẹyin gbogbo akọlu yii ki wọn jawọ ninu rẹ, nitori ikọlu si Igboho tumọ si pe gbogbo awọn ọmọ Yoruba ti wọn n ja fun ilẹ wọn ni wọn n kọ lu. O si jẹ ohun to buru jai pe ijọba yii ko ni amumọra rara fun ero awọn eeyan lori ohun to n lọ.

Aarẹ ni ninu ifimu-finlẹ oun loun ti gbọ pe awọn ṣọja atawọn janduku lati orileede mi-in ni wọn wa nidii ikọlu naa. O waa kilọ pe bi wọn ba pa Igboho, itajẹsilẹ ati ogun ni wọn n kọwe si yẹn, bii ti ogun Boko Haram to n ṣẹlẹ nilẹ  Hausa.

Leave a Reply