Big Brother Naija: Ọlamilekan lo ko owo rẹpẹtẹ lọọ ba mama ẹ nile

Aderounmu Kazeem

Orukọ a maa ro ni o, bẹẹ gan-an lọrọ Ọlamilekan Agbeleshe ṣe ri nigba ti wọn kede pe oun lo jawe olubori ninu idije eto kan to waye lori DSTV, ti wọn pe ni Big Brother Naija lockdown apa karun-un.

Miliọnu marundinlaaadorun-un (85m) ni ọdọmọkunrin ti ko ju ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, to tun jẹ ọmọ ipinlẹ Eko, yii jẹ. Ileewe giga Yunifasiti Eko lo ti pari, olorin taka-sufee loun naa.

Ni nnkan bii ọjọ mọkanlelaaadọrin sẹyin ni awọn eleto naa ko eeyan mọkandinlogun jọ sinu ile nla kan, oriṣiiriiṣi eto ni wọn si gbe kalẹ fun wọn. Koko agbekalẹ eto ọhun ni bi eeyan ṣe le ṣe laarin ọpọ eeyan, ifarada, iwa ọmọluabi atawọn ohun mi-in. Bakan naa ni awọn to ṣagbatẹru eto naa fun awọn eeyan ti wọn ko jọ yii laaye lati fẹra wọn, ti wọn si le bara wọn ṣere ifẹ daadaa.

Kinni kan waa ni o, laarin gbogbo awọn eeyan ti wọn ko jọ yii, Ọlamilekan, iyẹn Laycon, lawọn yooku maa n foju ẹgan ati yẹyẹ wo ju, wọn pe e loburẹwa danwo, ti wọn si lero wi pe ẹṣin ẹ ko le ta putu ninu idije naa.

Ọkọọkan ti ọmọ ọwọ n yọ ni wọn fi eto ọhun ṣe bi ọjọ ti ṣe n gori ọjọ, bẹẹ lawọn eeyan to wa nile naa ko ṣai ni ipa pataki ti wọn n ko. Awọn gan-an ni wọn n dibo fun ẹnikẹni ti wọn ba fẹ ko ṣi wa ninu idije naa. Bi ibo ba si ṣe n pọ si i fun eeyan lọsọọsẹ, bẹẹ ni yoo ṣe maa pẹ ninu idije ọhun si.

Lara ohun to mu Ọlamilekan jawe olubori ni bi ọpọ awọn oṣere tiata, awọn olorin ṣe to si i lẹyin, ti wọn si n kede ẹ fun araalu pe oun ni ki wọn maa dibo wọn fun.

Lara awọn oṣere ti wọn tẹle Laycon ni, Enila Badmus, Nkechi Blessing, dunlade Adekla, Broda Shaggi, Small Doctor, eyi dun, Woli AgbaFunmi Awlwa atawọn mi-in loriṣiiriiṣi.

Ṣinkin ni inu Iya Lekan yoo maa dun bayii, nitori ọmọ ẹ paapaa a maa sọrọ mama naa daadaa ni gbogbo ọjọ ti wọn fi ti wọn pa mọnu yara nla ọhun.

Leave a Reply