Bijọba ba fẹ, wọn le fun Seriki Fulani laaye lọdọ wọn, ṣugbọn ko gbọdọ wọ Igangan mọ – Ọladokun

Faith Adebọla

Oludasilẹ ati adari ẹgbẹ awọn ọdọ ilu Igangan, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, Ọgbẹni Ọladiran Ọladokun, ti sọ pe tefetefe lawọn le olori awọn Fulani ipinlẹ Ọyọ, Salihu AbdulKadir, kuro nilu naa, ati pe gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un lati ri i pe ọkunrin naa ko tun fẹsẹ tẹ ilu Igangan mọ.

O ni tijọba ba fẹ, wọn le lọọ fun un laaye nile ijọba, ṣugbọn ki Seriki Fulani naa ma ṣe dabaa pe oun maa pada waa gbe pẹlu awọn eeyan Ibarapa mọ, tori gbogbo wọn lawọn ti fẹnu ko si lile e lọ, gbogbo ọna si lawọn eeyan Ibarapa maa fi ri i pe eegun rẹ ko tun ṣẹ yọ niluu naa mọ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee yii, ni oludasilẹ ẹgbẹ ti wọn n pe ni Igangan Development Advocates, naa ba ALAROYE sọrọ. O ni oore nla ni igbesẹ ti ajijagbara nni, Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, ṣe fun agbegbe naa, tori wiwa tọkunrin naa wa lo ki awọn laya lati wọ ibuba wọn kan, iyẹn ile akọku kan to jẹ tijọba ipinlẹ Ọyọ ti wọn n pe ni Adamond, to wa lagbegbe ọhun. O ni ibẹ lawọn Fulani fi ṣe ọkan lara ibuba wọn, oriṣiiriṣii nnkan ija ti wọn n lo ni wọn ba nibẹ.

O ni latigba ti wọn ti le awọn Fulani afurasi ọdaran naa kuro niluu lọsẹ to kọja lọhun-un ni nnkan ti bẹrẹ si i yatọ lagbegbe naa, tawọn ko ti i tun gburoo pe awọn Fulani n dun mọhurumọhuru mọ wọn lọna iṣẹ oojọ wọn.

Nigba ta a bi i leere ero rẹ tijọba ba paṣẹ pe ki Seriki naa pada siluu, o ni: “Iyẹn o ṣoro, ijọba naa lo maa ba a wa aaye sileejọba. Wọn le fun un nilẹ tabi ki wọn tiẹ kọle fun un si Government House, n’Ibadan, tabi ilẹ to jẹ tijọba. A o binu siyẹn. Ṣugbọn lori ilẹ tiwa, laarin awa araalu nibi, o maa ṣoro gidi, mo si mọ pe oun naa o jẹ dabaa ẹ.”

Ọladiran ni igbesẹ tijọba fẹẹ gbe lati fi awọn ẹṣọ Amọtẹkun bii igba (200) ṣọwọ sagbegbe ọhun dara, bo tilẹ jẹ pe ọkan awọn eeyan ko ti i balẹ lati lọ ṣenu iṣẹ oko wọn bii ti tẹlẹ, tori ibẹru pe awọn Fulani kan ṣi le wa ninu igbo lati ṣe wọn ni ṣuta.

O waa rọ ijọba lati tete ṣiṣẹ lori fifi awọn ẹṣọ Amọtẹkun naa ranṣẹ, ki wọn si tubọ ṣe iwadii ijinlẹ lori awọn Fulani ati araalu to ba gbabọde lati mu ipenija ọrọ aabo agbegbe naa wa sopin.

Leave a Reply