Bijọba ko ba tete da si bi awọn ọdọ Yoruba ṣe n dojukọ awọn Fulani, o ṣee ṣe kawon eeyan wa naa gbẹsan-Ẹgbẹ Arewa

Olupolongo apapọ fun ẹgbẹ awọn Hausa ti wọn n pe ni Arewa Consultative Forum, Emmanuel Yaweh,  ti bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe doju ija kọ awọn Fulani ni ilẹ Yoruba, wọn ni iru igbesẹ bẹẹ le da orileede yii ru patapata. Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu bi awọn ẹṣọ alaabo ṣe kawọ gbera, ti wọn ko ṣe ohunkohun lasiko ti ikọlu naa n lọ lọwọ.

Lọjọ Abamẹta, Satide, lo sọrọ yii, o ni bi ogun abẹle ṣe berẹ diẹ diẹ naa ni wahala to bẹrẹ laarin awọn Fulani atawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ yii.

Emmanuel ni, ‘’Laaarọ yii la gbọ ẹsun pe awọn ọdọ Yoruba kọ lu Alaaji Saliu Abdulkadir to jẹ Seriki Fulani nipinlẹ Ọyọ, ninu ẹsun naa la ti gbọ pe wọn kọ lu ile rẹ, wọn si le e jade nile. Mọto mọkanla ni wọn dana sun, ti wọn si dana sun ile rẹ pẹlu, debii pe inu igbo ni oun atawọn mọlẹbi rẹ n sun bayii.

‘‘Ohun ta a gbọ ni pe ọkunrin kan to pe ara rẹ ni Sunday Igboho to n ja fun idasilẹ Oodua Republic, to si fun awọn Fulani ni gbedeke ọjọ meje lati kuro ni ilẹ Yoruba lo wa nidii gbogbo wahala naa.

‘‘Eyi to kọ eeyan lominu ju ninu ọrọ yii ni pe niṣe ni  awọn ẹsọ alaabo ti wọn ti gbọ nipa iwa ti ọkunrin yii feẹ hu ọhun kawọ gbera, ti wọn ko si ṣe ohunkohun lasiko ti ikọlu naa fi n lọ lọwọ.’’

‘‘Igbesẹ yii kọ ẹgbẹ Arewa lominu, a si n ke si ijọba apapọ ati ti ipinle nilẹ Yoruba lati dawọ iwa to le da rukerudo silẹ duro. Bẹ o ba gbagbe, awọn idojukọ lọlọkan-o-jọkan bii iru eyi lo da ogun abẹle silẹ lọjọsi.

‘’Ijọba gbọdọ gbe igbesẹ ti iru eyi ko fi ni i ṣẹlẹ, ki wọn si ri i pe wọn mu awọn to wa nidii wahala yii, ki wọn si fi iya to tọ jẹ wọn labẹ ofin. Bi wọn ba kuna lati ṣe beẹ, awọn eeyan Oke-Ọya naa le fẹẹ gbẹsan wahala naa, ti yoo si ko orileede yii sinu iyọnu gidi. Awọn alaṣẹ gbọdọ tete wa nnkan ṣe si i, nitori ọrọ yii n kọ ẹgbẹ AREWA lominu gidigidi.’’ Bẹẹ ni Emmanuel sọ.

 

Leave a Reply