Bireeki tanka epo feeli, lo ba tẹ awọn ọmọleewe mẹẹẹdogun pa

Faith Adebọla

Iran buruku ni iran ọhun, iran ti ko dun un wo rara, tori teeyan ba jẹ ori awun, aanu abiyamọ aa ṣe e ni, pẹlu bi ijamba ọkọ tanka epo kan to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, ṣe sọ mẹẹẹdogun lara awọn ọmọ ileewe pamari ti wọn n pada lọ sile wọn jẹẹjẹ doloogbe lojiji, niṣe lọkọ naa lọ gbogbo wọn mọlẹ bii ẹran aijẹ. Wọn ni mẹta ninu awọn ọmọ ohun lo jẹ pe baba kan naa, iya kan naa, lo bi wọn.

Yatọ sawọn to ku, ba a ṣe gbọ, awọn ọmọleewe bii marun-un mi-in tun fara pa gidi, ti wọn si wa lẹsẹ-kan-aye-ẹsẹ-kan-ọrun lọsibitu awọn ologun to wa ni Bareke David Ejoor, ni Effurun, ati ni ọsibitu Jẹnẹra Warri, ti wọn gbe wọn digbadigba lọ.

Wọn ni ileewe Army Children Primary School, to wa lagbegbe Effurun, nipinlẹ Delta, lawọn ọmọ naa ti n kawe, wọn o si ṣẹṣẹ maa rin ẹgbẹ titi naa, ibẹ ni wọn n gba lojoojumọ ti wọn ba n lọ sileewe tabi dari sile.

Nnkan bii aago meji aabọ ọsan ni tirela tanka ti epo bẹntiroolu kun inu rẹ bamu padanu ijanu rẹ, awakọ naa ko le ṣakoso ọkọ ọhun mọ, lo ba n ya barabara kaakiri, bo ṣe lọọ ya ba awọn ọmọleewe to n ṣeri pada lọ sile kaluku wọn niyẹn, o si pa wọn nifọnna ifọnṣu.

Gẹrẹ tiṣẹlẹ yii waye ni dẹrẹba ọkọ naa ti fẹsẹ fẹ ẹ, o sa lọ rau.

Ẹnikan tọrọ naa ṣoju ẹ sọ pe bireeki ọkọ ọhun lo feeli bo ṣe n da gẹrẹgẹrẹ ọna naa bọ, ti ko si le ṣakoso irin ọkọ naa, debi ti ijamba yii fi waye.

A gbọ pe awọn ileeṣẹ panapana ati awọn agbofinro to tete de sibi iṣẹlẹ naa ni ko jẹ kawọn ọdọ tinu n bi dana sun ọkọ ọhun, tori epo bẹntiroolu kun inu rẹ tẹmutẹmu.

Leave a Reply