Bisi Akande atawọn agbaagba APC ilẹ Yoruba kan ṣepade bonkẹlẹ pẹlu Buhari

Jide Alabi

Titi di asiko yii lẹnikan ko ti i le sọ koko ipade ti Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn agbaagba oṣelu APC kan ṣe nile ijọba, niluu Abuja, lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Gbọn-in-gbọn-in ni wọn ti ilẹkun pa ni kete ti wọn ti ko sinu yara pẹlu Aarẹ Buhari, ti ẹnikẹni ko si mọ ohun ti wọn fẹẹ jiroro le lori.

Alagba Bisi Akande ni wọn sọ pe o ko awọn agbaagba ninu ẹgbẹ APC ọhun ṣodi waa ṣepade pẹlu Muhammadu Buhari. Lara awọn agbaagba ọhun ni, Oluṣẹgun Ọṣọba, Ọmọọba Tajudeen Olusi ati Dokita Finnih pẹlu Bisi Akande, gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ.

Gbogbo akitiyan awọn oniroyin lati gbọ koko ipade wọn ni wọn kọ lati sọ nile ijọba ti wọn ti waa pade Buhari.

 

Leave a Reply