Bisi Akande gbalejo Tinubu, Arẹgbẹṣọla ati Gomina Oyetọla, wọn ni ija ni wọn lọọ pari

Nipinlẹ Ọṣun, niluu Ila Ọrangun, ni ipade kan ti waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, laarin Aṣiwaju Bọla Tinubu, Gomina Adegboyega Oyetọla, Rauf Arẹgbẹṣọla ati Oloye Bisi Akande.

ALAROYE gbọ pe ohun ti wọn tori ẹ pe ipade ọhun ni lati pẹtu si ija to wa laarin Oyetọla, ẹni ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọsun ati Rauf Arẹgbẹṣọla, to gbe ipo ọhun silẹ fun un lẹyin to lo ọdun mẹjọ gbako.

Ṣa o, ohun ti Arẹgbẹṣọla kọ sori ikanni abẹyẹfo ẹ ni pe oun ati awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle ti de si ipinlẹ Ọṣun bayii lati ṣepade pẹlu awọn eeyan pataki kan gẹgẹ bi Aarẹ Buhari ṣe pa oun laṣẹ, ṣugbọn awọn tọrọ ọhun ye daadaa sọ pe ija oun ati gomina ni wọn waa pari.

Aregbẹṣọla sọ pe, “Awọn ikọ ta a jọ wa ko ṣai ṣabẹwo si aṣaaju wa, Baba Bisi Akande, bakan naa la kan si Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, niluu Ila Ọrangun. Nibẹ naa ni baba ti ba wa sọrọ nipa awọn to ṣewọde ta ko ẹṣọ agbofinro SARS, ọrọ nipa eto aabo atawọn nnkan mi-in.”

Leave a Reply