Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ obinrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Blessing Jimoh, lori ẹsun pipa iya rẹ, Abilekọ Njeoma Odo, sinu oko n’Ilẹ-Oluji, nijọba ibilẹ Ilẹ-Oliji /Oke-Igbo.
Iya ọlọmọ mẹrin ọhun ni wọn lo sa mama agbalagba naa ladaa pa mọ inu oko lasiko ti wọn n ṣiṣẹ lọwọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.
Afurasi naa ni wọn ṣafihan rẹ ni olu ileesẹ wọn to wa lagbegbe Alagbaka, niluu Akurẹ, lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.
Nigba ta a si n fọrọ wa Blessing lẹnu wo, oun funra rẹ jẹwọ pe loootọ loun pa iya oun nibi tawọn ti jọ n ṣiṣẹ, ada lo ni oun fi dumbu obinrin to wa lati ipinlẹ Enugu ọhun bii ẹran bo tilẹ jẹ pe oun ti ṣe kinni ọhun tán ki oju oun too walẹ.
Lati bii ọdun diẹ sẹyin lo ni arun ọpọlọ ti n yọ oun lẹnu, ó ni ṣọọsi kan ti oun ti lọọ gbadura ni pasitọ ti jẹ ko ye oun pe ajẹ ni iya ọhun.
O ni ọpọ igba loun ti gbe igbesẹ ati bẹ ẹ, ṣugbọn ti ko si ayipada rara lori ọrọ aisan naa.
Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ, Bọlaji Salami, ti ni o di dandan ki ọdaran ọhun foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii awọn ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.