Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Atimọle, lọdọ awọn ọlọpaa, ni Blessing Ebuneku wa bayii nipinlẹ Ogun. Bẹẹ naa si ni Kọlawọle Imọlẹayọ ti wa ni gbaga pẹlu, nitori oun lo ṣatọna bi Blessing ṣe ta awọn ọmọ rẹ obinrin meji ni tiri ọndirẹdi taosan, ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira, to ni nitori ọkọ oun to tirafu fọdun meji ni.
Ọkọ Blessing, Oluwaṣeyi Agoro, lo mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa ẹka Redeemed Camp, nipinlẹ Ogun, pe oun rinrin-ajo fasiko kan, oun fi Blessing atawọn ọmọ meji to bi foun silẹ nile. O ni nigba toun de, oun ko ba awọn ọmọbinrin meji naa torukọ wọn n jẹ Ṣemiloore Agoro, ọmọ ọdun mẹrin, ati Deborah Agoro; omọ ọdun meji.
Ọgbẹni Agoro ni gbogbo boun ṣe beere lọwọ iyawo oun ti i ṣe iya wọn to, ko jẹwọ ibi tawọn ọmọ naa wa. O ni nigba to su oun loun waa fẹjọ rẹ sun ni teṣan, kawọn ọlọpaa le ba oun beere ibi ti ko awọn ọmọ lọ.
Awọn ọlọpaa dele awọn tọkọ-taya Agoro, wọn mu Blessing, wọn si fọrọ wa a lẹnu wo. Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, obinrin ẹni ọdun marundinlogoji naa sọ pe oun ti bimọ meji fọkunrin kan tẹlẹ koun too fẹ Ṣeyi, o ni pẹlu meji toun bi fun Agoro yii, wọn di mẹrin, bukaata wọn si wa lọrun oun.
O ni nigba ti Agoro waa tirafu fọdun meji ti ko boju wẹyin, ti atijẹ-atimu si ṣoro foun pẹlu awọn ọmọ mẹrin loun dọgbọn si ọrọ ara oun.
Blessing sọ pe lasiko toun n ro ohun toun le ṣe ni Kọlawọle Imọlẹayọ ti wọn jọ mu awọn yii, waa sọ foun pe awọn tọkọ-taya kan wa ni Port- Harcourt, nilẹ Ibo lọhun-un ti wọn ko rọmọ bi, ti wọn si le ra meji ninu awọn ọmọ oun yii ti wọn yoo sanwo gidi foun.
Iyawo Agoro tẹsiwaju pe bi Kọlawọle ṣe ba oun to o niyẹn ti awọn ọmọ meji naa kọja si Pọta lọhun-un, awọn to ra wọn si san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (300,000) foun gẹgẹ bii owo ọmọ meji.
Bo ti jẹwọ yii ni awọn ọlọpaa lọọ mu Kọlawọle Imọleayọ to ba a ṣeto onibaara yii, wọn ju oun naa si ẹyin gbaga.
Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Edward Ajọgun ti ni ki wọn ri i pe wọn gba awọn ọmọde meji naa pada wale kia, ki wọn si ko Blessing ati Kọlawọle lọ sẹka to n gbọ ẹjọ awọn to ba n fọmọ ṣowo bii tiwọn.