Bobby Ese lorukọ ọkunrin yii, ṣugbọn Aladja Chief Priest lawọn eeyan mọ ọn si nijọba ibilẹ Guusu Warri to n gbe. Ibẹ naa lo ti ko sodo ti wọn n pe ni Ugbokodo, nipinlẹ Delta. Niṣe lo sọ pe oun ṣaa gbọdọ ku lọjọ naa, nitori oun ko fẹran mọlẹbi, oun ko fẹẹ ba wọn ṣe.
Ko sẹni to mọ ẹbi ti ọkunrin yii n tọka si, ohun to han sawọn eeyan ko ju pe lọjọ ti Bobby ku yii, o kọ akọle ibẹru kan si ẹka ayelujara rẹ, lapa ibi ti wọn n pe ni ‘Status’.
Ohun to kọ sibẹ ni pe oun maa ku lọjọ naa, oun koriira mọlẹbi.
Loke ohun to kọ naa lo fi fọto kan si, faanu inu yara rẹ to so okun mọ ni, eyi to fi han pe o ti kọkọ fẹẹ pokunso tẹlẹ, ko si gba ẹmi lẹnu ara ẹ .
Nigba to ya lo tun ero rẹ pa, ti ko pokunso mọ. Ṣugbọn nitori o loun yoo ṣaa ku lọjọ naa, niṣe ni Bobby, ẹni tọjọ ori ẹ ko ti i to mẹẹẹdọgbọn (25) gba odo Ugbokodo lọ, o si bẹ sodo nla naa nigba tawọn eeyan ko si nibẹ, n lomi ba pitu ọwọ ẹ fun un.
Bobby ku lọjọ to loun yoo ku, ko si sohun ti mọlẹbi tabi ẹnikẹni le ṣe si i.
Bawọn eeyan ẹ ṣe n wadii ohun to fa a to fi gbe igbesẹ buruku yii.